The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Opening [Al-Fatiha] - Yoruba translation
Surah The Opening [Al-Fatiha] Ayah 7 Location Maccah Number 1
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]
Gbogbo ẹyìn[1] ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa² gbogbo ẹ̀dá (àgbáńlá ayé àti ọ̀run),
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
Ọba Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá ìrànlọ́wọ́ (àti oore) sí.
Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (ẹ̀sìn ’Islām),
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún, yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).