عربيEnglish

The Noble Qur'an Encyclopedia

Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languages

The Disbelievers [Al-Kafiroon] - Yoruba translation

Surah The Disbelievers [Al-Kafiroon] Ayah 6 Location Maccah Number 109

Sọ pé: “Ẹ̀yin aláìgbàgbọ́,

Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.

Ẹ̀yin náà kò jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ jọ́sìn fún sẹ́.

Ẹ̀yin náà kò kú jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

Tiyín ni ẹ̀sìn yín, tèmi sì ni ẹ̀sìn mi.”