The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Prostration [As-Sajda] - Yoruba translation
Surah The Prostration [As-Sajda] Ayah 30 Location Maccah Number 32
’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.[1]
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fún yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà.[1]
Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
Ẹni tó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú ẹrẹ̀.
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ.
Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá).[1] Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá!
Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.
Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A yàn fún yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”[1]
(Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”
Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín (sínú Iná). Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]
Àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga.
Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn jìnnà sí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.
Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).
Ǹjẹ́ ẹni tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni tó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba.
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).
Ní ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”[1]
Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà tó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà tó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn).
Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí o ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀).[1] A sì ṣe Tírà A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
Àti pé A ṣe àwọn kan nínú wọn ní Imām (aṣíwájú) tí wọ́n ń fi àṣẹ Wa (ohun tí A pa wọ́n ní àṣẹ rẹ̀ nínú at-Taorāh) tọ́ àwọn ènìyàn wọn sí ọ̀nà òdodo. (A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.
Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)?
Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni?
Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí lọ́ wọn lára láti ronúpìwàdà.”.”[1]
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀).