The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Troops [Az-Zumar] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 3
Surah The Troops [Az-Zumar] Ayah 75 Location Maccah Number 39
أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ [٣]
Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.[1] Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): “A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni.” Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.