The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Women [An-Nisa] - Yoruba translation
Surah The Women [An-Nisa] Ayah 176 Location Madanah Number 4
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.
Ẹ fún àwọn ọmọ òrukàn ní dúkìá wọn.[1] Ẹ má ṣe fi n̄ǹkan dáadáa pààrọ̀ n̄ǹkan burúkú.² Ẹ sì má ṣe jẹ dúkìá wọn mọ́ dúkìá yín; dájúdájú ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi.
Tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé nípa (fífẹ́) ọmọ òrukàn,[1] ẹ fẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ si yín nínú àwọn obìnrin; méjì tàbí mẹ́ta tàbí mẹ́rin.² Ṣùgbọ́n tí ẹ bá páyà pé ẹ ò níí ṣe déédé, (ẹ fẹ́) ẹyọ kan tàbí ẹrúbìnrin yín. Ìyẹn súnmọ́ jùlọ pé ẹ ò níí ṣàbòsí.
Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn tó jẹ́ ọ̀ran-anyàn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fún yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.
Ẹ má ṣe kó dúkìá yín tí Allāhu fí ṣe gbẹ́mìíró fún yín lé àwọn aláìlóye lọ́wọ́. Ẹ pèsè ìjẹ-ìmu fún wọn nínú rẹ̀, kí ẹ sì raṣọ fún wọn. Kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Ẹ dán àwọn ọmọ òrukàn wò[1] títí wọn yóò fi dàgbà wọ ẹni tí ò lè ṣe ìgbéyàwó.² Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.
Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).
Nígbà tí àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù bá wà ní (ìjókòó) ogún pípín, ẹ fún wọn nínú rẹ̀ (ṣíwájú kí ẹ tó pín ogún), kí ẹ sì sọ̀rọ̀ dáadáa fún wọn.
Àwọn (olùpíngún àti alágbàwò-ọmọ-òrukàn) tí ó bá jẹ́ pé àwọn náà máa fi ọmọ wẹ́wẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì ń páyà lórí wọn, kí wọ́n yáa bẹ̀rù Allāhu. Kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ dáadáa (fún ọmọ òrukàn).
Dájúdájú àwọn tó ń jẹ dúkìá ọmọ òrukàn pẹ̀lú àbòsí, Iná kúkú ni wọ́n ń jẹ sínú ikùn wọn. Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
Allāhu ń sọ àsọọ́lẹ̀ (òfin) fún yín nípa (ogún tí ẹ máa pín fún) àwọn ọmọ yín; ti ọkùnrin ni irú ìpín ti obìnrin méjì. Tí wọ́n bá sì jẹ́ obìnrin (nìkan), méjì sókè, tiwọn ni ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ohun tí (òkú) fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ obìnrin kan ṣoṣo, ìdajì ni tirẹ̀. Ti òbí rẹ̀ méjèèjì, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì nínú ohun tí òkú fi sílẹ̀, tí ó bá ní ọmọ láyé. Tí kò bá sì ní ọmọ láyé, tí ó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì l’ó máa jogún rẹ̀, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ni ti ìyá rẹ̀. Tí ó bá ní arákùnrin (tàbí arábìnrin), ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìyá rẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ó sọ tàbí gbèsè. Àwọn bàbá yín àti àwọn ọmọkùnrin yín; ẹ̀yin kò mọ èwo nínú wọn ló máa mú àǹfààní ba yín jùlọ. (Ìpín) ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Tiyín ni ìlàjì ohun tí àwọn ìyàwó yín fi sílẹ̀, tí wọn kò bá ní ọmọ. Tí wọ́n bá sì ní ọmọ, tiyín ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè. Tiwọn sì ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́rin ohun tí ẹ fi sílẹ̀, tí ẹ̀yin kò bá ní ọmọ láyé. Tí ẹ bá ní ọmọ láyé, ìdá kan nínú ìdá mẹ́jọ ni tiwọn nínú ohun tí ẹ fi sílẹ̀ lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí ẹ sọ tàbí gbèsè. Tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan tí wọ́n fẹ́ jogún rẹ̀ kò bá ní òbí àti ọmọ, tí ó sì ní arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan, ìdá kan nínú ìdá mẹ́fà ni ti ìkọ̀ọ̀kan àwọn méjèèjì. Tí wọ́n bá sì pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ, wọn yóò dìjọ pín ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta, lẹ́yìn àsọọ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tàbí gbèsè, tí kò níí jẹ́ ìpalára. Àsọọ́lẹ̀ (òfin) kan ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Aláfaradà.
Ìyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (tí) Allāhu (gbékalẹ̀ fún ogún pípín). Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ó sì ń tayọ àwọn ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú Iná kan. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì ń bẹ fún un.[1]
Àwọn tó ń ṣe sìná nínú àwọn obìnrin yín, ẹ wá ẹlẹ́rìí mẹ́rin nínú yín tí ó máa jẹ́rìí lé wọn lórí. Tí wọ́n bá jẹ́rìí lé wọn lórí, kí ẹ dè wọ́n mọ́ inú ilé títí ikú yóò fi pa wọ́n tàbí (títí) Allāhu yóò fi gbé ọ̀nà (ìjìyà) kan kalẹ̀ fún wọn.[1]
Àwọn méjì tí wọ́n ṣe sìná nínú yín, kí ẹ (fi ẹnu tàbí ọwọ́) bá wọn wí.[1] Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣàtúnṣe, kí ẹ mójú kúrò lára wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́- ọ̀run.
Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan.[1] Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́ (ìyẹn ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn). Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Kò sí ìronúpìwàdà fún àwọn tó ń ṣe aburú títí ikú fi dé bá ọ̀kan nínú wọn, kí ó wá wí pé: “Dájúdájú èmi ronú pìwàdà nísisìnyìí.” (Kò tún sí ìronúpìwàdà) fún àwọn tó kú sípò aláìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyẹn, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta eléro sílẹ̀ dè wọ́n.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má ṣe fúnlẹ̀ mọ́ wọn nítorí kí ẹ le gba apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.
Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn(tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?[1]
Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè gbà á padà nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ ti wọlé tọ’ra yín, tí wọ́n sì ti gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ yín![1]
Ẹ má ṣe fẹ́ ẹni tí àwọn bàbá yín ti fẹ́ nínú àwọn obìnrin àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ àti ohun ìkórira. Ó sì burú ní ọ̀nà.
A ṣe é ní èèwọ̀ fún yín (láti fẹ́) àwọn ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin yín àti àwọn arábìnrin yín àti àwọn arábìnrin bàbá yín àti àwọn arábìnrin ìyá yín àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin yín àti àwọn ìyá yín tí ó fún yín ní ọyàn mu àti àwọn arábìnrin yín nípasẹ̀ ọyàn àti àwọn ìyá ìyàwó yín àti àwọn ọmọbìnrin ìyàwó yín tí ẹ gbà tọ́, èyí tó wà nínú ilé yín,[1] tí ẹ sì ti wọlé tọ àwọn ìyá wọn, - tí ẹ̀yin kò bá sì tí ì wọlé tọ̀ wọ́n, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín (láti fẹ́ ọmọbìnrin wọn), - àti àwọn ìyàwó ọmọ yín, èyí tí ó ti ìbàdí yín jáde. (Ó tún jẹ́ èèwọ̀) láti fẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò papọ̀ àyàfi èyí tí ó ti ré kọjá. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(Ó tún jẹ́ èèwọ̀ láti fẹ́) àwọn abilékọ nínú àwọn obìnrin àyàfi àwọn ẹrúbìnrin yín. Òfin Allāhu nìyí lórí yín. Wọ́n sì ṣe ẹni tó ń bẹ lẹ́yìn àwọn wọ̀nyẹn (àwọn obìnrin yòókù) ní ẹ̀tọ́ fún yín pé kí ẹ wá wọn fẹ́ pẹ̀lú dúkìá yín; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ ìyàwó, láì nìí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì síso). Ẹni tí ẹ bá sì fẹ́ ní fífẹ́ ìyàwó nínú wọn, tí ẹ sì ti jẹ ìgbádùn oorun ìfẹ́ lára wọn[1] (àmọ́ tí ẹ fẹ́ kọ̀ wọ́n sílẹ̀), ẹ fún wọn ní sọ̀daàkí wọn tí ó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn.² Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ dìjọ yọ́nú sí (láti fojúfò láààrin ara yín) lẹ́yìn sọ̀daàkí (tó jẹ́ ìpín ọ̀ran-anyàn)³. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹni tí kò bá lágbára ọrọ̀ nínú yín láti fẹ́ àwọn olómìnira onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, kí ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúbìnrin yín onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ yín, ara kan náà sì ni yín. Nítorí náà, ẹ fẹ́ wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda àwọn olówó wọn (àwọn ọ̀gá wọn). Kí ẹ sì fún wọn ní sọ̀daàkí wọn ní ọ̀nà tó dára, (ìyẹn) àwọn ọmọlúàbí (ẹrúbìnrin), yàtọ̀ sí àwọn onísìná obìnrin àti àwọn obìnrin tí ń yan àlè[1]. Nígbà tí wọ́n bá sì di abilékọ, tí wọ́n bá (tún) lọ ṣe sìná, ìlàjì ìyà tí ń bẹ fún àwọn olómìnira obìnrin ni ìyà tí ń bẹ fún wọn.² (Fífẹ́ ẹrúbìnrin), ìyẹn wà fún ẹni tó ń páyà ìnira (sìná) nínú yín. Àti pé kí ẹ ṣe sùúrù lóore jùlọ fún yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Allāhu fẹ́ ṣàlàyé (òfin) fún yín, Ó fẹ́ tọ yín sí ọ̀nà àwọn tó ṣíwájú yín, Ó sì fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Àti pé Allāhu fẹ́ gba ìronúpìwàdà yín. Àwọn tó sì ń tẹ̀lé ìfẹ́-adùn ara sì ń fẹ́ kí ẹ yẹ̀ kúrò (nínú ẹ̀sìn) ní yíyẹ̀ tó tóbi pátápátá.
Allāhu fẹ́ gbé e fúyẹ́ fún yín; A sì ṣẹ̀dá ènìyàn ní ọ̀lẹ.[1]
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín àyàfi kí ó jẹ́ òwò ṣíṣe pẹ̀lú ìyọ́nú láààrin ara yín. Ẹ má ṣe para yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú si yín.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe ìyẹn láti fi tayọ ẹnu-ààlà àti láti fi ṣe àbòsí, láìpẹ́ A máa mú un wọ inú Iná. Ìrọ̀rùn sì ni ìyẹn jẹ́ fún Allāhu.
Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá tí A kọ̀ fún yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín, A sì máa mu yín wọ àyè alápọ̀n-ọ́nlé.
Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan.[1] Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu nínú àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Ìkọ̀ọ̀kan (nínú yín) ni A ti ṣe àdáyanrí àwọn ẹbí tí ó máa jogún rẹ̀ nínú ohun tí àwọn òbí àti ẹbí fi sílẹ̀. Àwọn tí ẹ sì búra fún (pé ẹ máa fún ní n̄ǹkan), ẹ fún wọn ní ìpín wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró[1] fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn⁴, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n (láì níí kó ìnira bá wọn). Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà⁵. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.⁶
Tí ẹ bà sì mọ̀ pé ìyapa wà láààrin àwọn méjèèjì, ẹ gbé olóye kan dìde láti inú ẹbí ọkọ àti olóye kan láti inú ẹbí ìyàwó. Tí àwọn (tọkọ tìyàwó) méjèèjì bá ń fẹ́ àtúnṣe, Allāhu yóò fi àwọn (olóye méjèèjì) ṣe kòǹgẹ́ àtúnṣe lórí ọ̀rọ̀ ààrin wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Alámọ̀tán.
Ẹ jọ́sìn fún Allāhu, ẹ má ṣe fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I. Ẹ ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì àti ẹbí àti àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù àti aládùúgbò tó súnmọ́ àti aládùúgbò tó jìnnà àti ọ̀rẹ́ alábàárìn àti onírìn-àjò (tí agara dá) àti àwọn ẹrú yín. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ onígbèéraga onífáàrí.
Àwọn tó ń ṣahun, (àwọn) tó ń pa ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe àti (àwọn) tó ń fi ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ pamọ́; A ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn tó ń ná dúkìá wọn pẹ̀lú ṣekárími, tí wọn kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ẹnikẹ́ni tí aṣ-Ṣaetọ̄n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ fún, ó burú ní ọ̀rẹ́.
Kí ni ìpalára tí ó máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí wọ́n sì ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún wọn? Allāhu sì jẹ́ Onímọ̀ nípa wọ́n.
Dájúdájú Allāhu kò níí ṣàbòsí òdíwọ̀n ọmọ iná-igún. Tí ó bá jẹ iṣẹ́ rere, Ó máa ṣàdìpèlé (ẹ̀san) rẹ̀. Ó sì máa fún (olùṣe rere) ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
فَكَيۡفَ إِذَا جِئۡنَا مِن كُلِّ أُمَّةِۭ بِشَهِيدٖ وَجِئۡنَا بِكَ عَلَىٰ هَٰٓؤُلَآءِ شَهِيدٗا [٤١]
Báwo ni ọ̀rọ̀ wọn yóò ti rí nígbà tí A bá mú ẹlẹ́rìí jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí A sì mú ìwọ jáde ní ẹlẹ́rìí lórí àwọn wọ̀nyí?
Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì yapa Òjíṣẹ́ náà, wọ́n á fẹ́ kí àwọn bá ilẹ̀ dọ́gba (kí wọ́n di erùpẹ̀). Wọn kò sì lè fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́ fún Allāhu.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe súnmọ́ ìrun kíkí nígbà tí ọtí bá ń pa yín títí ẹ máa fi mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ[1] àti àwọn oníjánnábà, àfi àwọn olùkọjá nínú mọ́sálásí, títí ẹ máa fi wẹ̀ (ìwẹ̀ jánnábà). Tí ẹ bá sì jẹ́ aláìsàn tàbí ẹ wà lórí ìrìn-àjò tàbí ẹnì kan nínú yín dé láti ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tàbí ẹ súnmọ́ obínrin (yín), tí ẹ kò rí omi, ẹ fi erùpẹ̀ tó dára ṣe táyàmọ́mù; ẹ fi pá ojú yín àti ọwọ́ yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń ra ìṣìnà, tí wọ́n sì fẹ́ kí ẹ ṣìnà lójú-ọ̀nà?
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe.
Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn tó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́rọ̀ bí ẹni tí etí rẹ̀ ti di, òmùgọ̀ wa.”[1] Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
Ẹ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ.
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I.[1] Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí wọn.[1]
Wo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un.
Tàbí ìpín kan ń bẹ fún wọn nínú ìjọba (Wa) ni? Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ wọn kò níí fún àwọn ènìyàn ní (òdiwọ̀n) àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú (ní ibi tí wọ́n máa yahun dé).
Tàbí wọ́n ń ṣe ìlara àwọn ènìyàn lórí ohun tí Allāhu fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀ ni? Dájúdájú A fún àwọn ẹbí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (sunnah). A sì fún wọn ní ìjọba ńlá.
Nítorí náà, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣẹ́rí kúrò níbẹ̀. Jahanamọ sì tó ní iná tó ń jo.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, láìpẹ́ A máa mú wọn wọ inú Iná. Ìgbàkígbà tí awọ ara wọn bá jóná, A óò máa pààrọ̀ awọ ara mìíràn fún wọn kí wọ́n lè máa tọ́ ìyà wò lọ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, A óò mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Àwọn ìyàwó mímọ́ ń bẹ fún wọn nínú rẹ̀. A sì máa fi wọ́n sí abẹ́ ibòji tó máa ṣíji bò wọ́n dáradára.
Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ dá àgbàfipamọ́ padà fún àwọn olówó wọn. Àti pé nígbà tí ẹ bá ń dájọ́ láààrin àwọn ènìyàn, ẹ dájọ́ pẹ̀lú déédé. Dájúdájú Allāhu ń fi n̄ǹkan tó dára ṣe wáàsí fún yín. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -,[1] tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀ (ìyọrísí).
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ (tí kò sì rí bẹ́ẹ̀) pé dájúdájú àwọn gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, tí wọ́n sì ń gbèrò láti gbé ẹjọ́ lọ bá òrìṣà, A sì ti pa wọ́n láṣẹ pé kí wọ́n lòdì sí i. Aṣ-ṣaetọ̄n sì fẹ́ ṣì wọ́n lọ́nà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá síbi ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ẹ wá bá Òjíṣẹ́.”, o máa rí àwọn mùnááfìkí tí wọn yóò máa ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ rẹ tààrà.
Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọ́n tì síwájú, lẹ́yìn náà wọ́n máa wá bá ọ, wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé kò sí ohun tí a gbàlérò bí kò ṣe dáadáa àti ìrẹ́pọ̀.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣe wáàsí fún wọn, kí o sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó máa mì wọ́n lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ ara wọn.
A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ,[1] wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Rárá, Èmi fi Olúwa rẹ búra pé wọn kò tí ì gbàgbọ́ ní òdodo títí wọn yóò fi gbà ọ́ ní olùdájọ́ lórí ohun tí ó bá dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Lẹ́yìn náà, wọn kò níí ní ẹ̀hónú kan sí ìdájọ́ tí o bá dá. Wọ́n sì máa gbà pátápátá.
Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní ọ̀ran- anyàn fún wọn pé: "Ẹ pa ara yín tàbí ẹ jáde kúrò nínú ìlú yín," wọn kò níí ṣe é àfi díẹ̀ nínú wọn. Tí ó bá tún jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun tí A fi ń ṣe wáàsí fún wọn ni, ìbá jẹ́ oore àti ìdúróṣinṣin tó lágbára jùlọ fún wọn.
Nígbà náà, dájúdájú Àwa ìbá fún wọn ní ẹ̀san ńlá láti ọ̀dọ̀ Wa.
Àti pé dájúdájú Àwa ìbá tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, àwọn olódodo, àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi[1] àti àwọn ẹni rere. Àwọn wọ̀nyẹn sì dára ní alábàárìn.
Oore àjùlọ yẹn máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu; Allāhu sì tó ní Onímọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú ohun ìṣọ́ra yín lọ́wọ́, kí ẹ sì tú jáde s’ójú ogun ẹ̀sìn níkọ̀níkọ̀ tàbí kí ẹ tú jáde ní àpapọ̀.[1]
Dájúdájú ó ń bẹ nínú yín ẹni tó ń fà sẹ́yìn. Tí àdánwó kan bá kàn yín, ó máa wí pé: “Allāhu kúkú ti ṣe ìdẹ̀ra fún mi nítorí pé èmi kò sí níbẹ̀ pẹ̀lú wọn (wọn kò sì rí mi pa pẹ̀lú àwọn tó kú ikú ṣẹhīdi).”
Dájúdájú tí oore àjùlọ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá sì tẹ̀ yín lọ́wọ́, dájúdájú ó máa sọ̀rọ̀ - bí ẹni pé kò sí ìfẹ́ láààrin ẹ̀yin àti òun (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) - pé: “Yéè! Èmi ìbá wà pẹ̀lú wọn, èmi ìbá jẹ èrè ńlá.”
Nítorí náà, kí àwọn tó ń fi ayé ra ọ̀run máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, yálà wọ́n pa á tàbí ó ṣẹ́gun, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.
Kí l’ó ṣe yín tí ẹ kò níí jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn Rẹ̀) àti (fún ààbò) àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń jagun sí ojú-ọ̀nà òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ja àwọn ọ̀rẹ́ aṣ-Ṣaetọ̄n lógun. Dájúdájú ète aṣ-Ṣaetọ̄n, ó jẹ́ ohun tí ó lẹ.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ káwọ́ ró (ẹ má ì jagun ẹ̀sìn, àmọ́) ẹ máa kírun, kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: “Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i.[1]” Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni tó bá bẹ̀rù Allāhu. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí yín.”²
Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé orí òkè ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí ló ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan.
Ohunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.[1]
Ẹnikẹ́ni tó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. Ẹnikẹ́ni tó bá sì pẹ̀yìndà, A kò rán ọ níṣẹ́ olùṣọ́ lórí wọn.
Wọ́n ń wí pé: “A tẹ̀lé àṣẹ rẹ.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ, igun kan nínú wọn máa pètepèrò ní òru n̄ǹkan mìíràn tí ó yàtọ̀ sí èyí tí ó ń sọ (ní ọ̀sán). Allāhu sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ń pètepèrò rẹ̀ ní òru. Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùgbáralé.
Ṣé wọn kò ronú nípa al-Ƙur’ān ni? Tí ó bá jẹ́ pé ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn yàtọ̀ sí Allāhu, wọn ìbá rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìtakora nínú rẹ̀.[1]
Nígbà tí ọ̀rọ̀ ìfàyàbalẹ̀ tàbí ìpáyà kan bá dé bá wọn, wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ àti àwọn aláṣẹ (ìyẹn, àwọn onímọ̀ ẹ̀sìn) nínú wọn, àwọn tó ń yọ òdodo jáde nínú ọ̀rọ̀ nínú wọn ìbá mọ̀ ọ́n. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín ni, ẹ̀yin ìbá tẹ̀lé aṣ-Ṣaetọ̄n àfi ìba díẹ̀ (nínú yín).[1]
Nítorí náà, jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò là á bọ ẹnì kan lọ́rùn àfi ìwọ. Kí o sì gbẹ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóǹgbẹ ogun ẹ̀sìn. Ó ṣeé ṣe kí Allāhu ká ọwọ́ ìjà àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ró. Àti pé Allāhu le jùlọ ní ogun. Ó sì le jùlọ níbi ìjẹni-níyà.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ rere, ó máa ní ìpín kan nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìpẹ̀ ìṣìpẹ̀ aburú, ó máa ní ìpín kan nínú rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan[1].
86. Nígbà tí wọ́n bá ki yín ní kíkí kan, ẹ kí wọn (padà) pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà (pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ki yín). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣírò lórí gbogbo n̄ǹkan.
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ta ló sọ̀dodo ọ̀rọ̀ ju Allāhu?
Kí ni ó máa mu yín pín sí ìjọ méjì nípa àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí! Ṣebí Allāhu l’Ó dá wọn padà sẹ́yìn[1] nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ṣé ẹ fẹ́ fi ẹni tí Allāhu ṣì lọ́nà mọ̀nà ni? Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò níí rí ọ̀nà kan fún un.
Wọ́n fẹ́ kí ẹ ṣàì gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́, kí ẹ lè jọ di ẹgbẹ́ kan náà. Nítorí náà, ẹ má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò nínú wọn títí wọ́n fi máa kúrò nínú ìlú ẹbọ wá sí ìlú ’Islām nítorí ẹ̀sìn Allāhu. Tí wọ́n bá kẹ̀yìn (sí ìgbàgbọ́ òdodo), ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Kí ẹ sì má ṣe mú ọ̀rẹ́ àyò àti olùrànlọ́wọ́ kan nínú wọn.
Àyàfi àwọn tó bá darapọ̀ mọ́ ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Tàbí wọ́n wá ba yín, tí ọkàn wọn ti pami láti ba yín jà tàbí láti bá àwọn ènìyàn wọn jà. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá fún wọn lágbára (ọkàn-akin) lórí yín, wọn ìbá sì jà yín lógun. Nítorí náà, tí wọ́n bá yẹra fún yín, tí wọn kò sì jà yín lógun, tí wọ́n sì juwọ́ sílẹ̀ fún yín, nígbà náà Allāhu kò fún yín ní ọ̀nà lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Ẹ máa rí àwọn ẹlòmíìràn tí wọ́n ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ yín (wọ́n bá ní àwọn gba ’Islām), wọ́n tún ń fẹ́ ààbò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọn (wọ́n tún ń bá wọn ṣẹbọ), ìgbàkígbà tí wọ́n bá dá wọn padà sínú ìfòòró (ìbọ̀rìṣà), wọ́n sì ń padà sínú rẹ̀. Tí wọn kò bá yẹra fún yín, tí wọn kò juwọ́ sílẹ̀ fún yín, tí wọn kò sì dáwọ́ jíjà yín lógun dúró, nígbà náà ẹ mú wọn, kí ẹ sì pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu sì fún yín ní agbára tó yanjú lórí wọn (láti jà wọ́n lógun).
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo kan láti pa onígbàgbọ́ òdodo kan àyàfi tí ó bá ṣèèsì. Ẹni tí ó bá sì ṣèèsì pa onígbàgbọ́ òdodo kan, ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ó tún máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn òkú àfi tí wọ́n bá fi tọrẹ (fún un, tí wọ́n bá yọ̀ǹda rẹ̀ fún un). Tí ó bá sì wà nínú àwọn ènìyàn kan tí ó jẹ́ ọ̀tá fún yín, onígbàgbọ́ sì ni (ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Tí ó bá jẹ́ ìjọ tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn (ni ẹni tí wọ́n ṣèèsì pa), ó máa san owó ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó tún máa tú ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo kan sílẹ̀ lóko ẹrú. Ẹni tí kò bá rí (ẹrú lónígbàgbọ́ òdodo), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. (Ọ̀nà) ìronúpìwàdà kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu (nìyí). Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa onígbàgbọ́ òdodo kan, iná Jahanamọ ni ẹ̀san rẹ̀. Olùṣegbére ni nínú rẹ̀. Allāhu yóò bínú sí i. Ó máa ṣẹ́bilé e. Ó sì ti pèsè ìyà ńlá sílẹ̀ dè é.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò ní ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ogun ẹ̀sìn), ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn). Ẹ sì má ṣe sọ fún ẹni tí ó bá sálámọ̀ si yín pé kì í ṣe onígbàgbọ́ òdodo látara pé ẹ̀yin ń wá dúkìá ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọ̀dọ̀ Allāhu kúkú ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọrọ̀ ogun wà. Báyẹn ni ẹ̀yin náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, Allāhu sì ṣe ìdẹ̀ra (ẹ̀sìn) fún yín. Nítorí náà, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí ẹ fi mọ òdodo (nípa àwọn ènìyàn náà). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn olùjókòó sínú ilé nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, yàtọ̀ sí àwọn aláìlera, àti àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn, wọn kò dọ́gba. Allāhu fi ipò kan ṣoore àjùlọ fún àwọn olùjagun ní ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé. Olúkùlùkù (wọn) ni Allāhu ṣe àdéhùn ohun rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) fún. Allāhu gbọ́lá fún àwọn olùjagun ẹ̀sìn lórí àwọn olùjókòó sínú ilé pẹ̀lú ẹ̀san ńlá;
àwọn ipò kan àti àforíjìn àti àánú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?[1]” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fún yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.
Àyàfi àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí kò ní ìkápá ọgbọ́n kan, wọn kò sì dá ọ̀nà mọ̀ (dé ìlú Mọdīnah).
Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn, ó súnmọ́ kí Allāhu ṣàmójúkúrò fún wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Aláforíjìn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ìlú rẹ̀ jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu, ó máa rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ibùsásí àti ìgbàláyè lórí ilẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ (tí ó jẹ́) olùfìlú-sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ikú bá a (lójú ọ̀nà), ẹ̀san rẹ̀ kúkú ti dúró lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.[1]
Nígbà tí ẹ bá ṣe ìrìn-àjò lórí ilẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín láti dín ìrun kù,[1] tí ẹ̀yin bá ń bẹ̀rù pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò fòòró yín. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, wọ́n jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
Nígbà tí o bá wà láààrin wọn, gbé ìrun dúró fún wọn. Kí igun kan nínú wọn kírun pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n mú n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá sì forí kanlẹ̀ (tí wọ́n parí ìrun), kí wọn bọ́ sẹ́yìn yín, kí igun mìíràn tí kò tí ì kírun wá kírun pẹ̀lú rẹ. Kí wọ́n mú ìṣọ́ra wọn[1] àti n̄ǹkan ìjagun wọn lọ́wọ́. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ fẹ́ kí ẹ gbàgbé àwọn n̄ǹkan ìjagun yín àti n̄ǹkan ìgbádùn yín (ẹrù oúnjẹ yín), kí wọ́n lè kọlù yín ní ẹ̀ẹ̀ kan náà. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín tí ó bá jẹ́ pé ìpalára kan ń bẹ fún yín látara òjò tàbí (pé) ẹ jẹ́ aláìsàn, pé kí ẹ fi n̄ǹkan ìjagun yín sílẹ̀ (lórí ìrun). Ẹ mú n̄ǹkan ìṣọ́ra yín lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu ti pèsè ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Nígbà tí ẹ bá parí ìrun, kí ẹ ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní ìdúró, ìjókòó àti ìdùbúlẹ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá sì fọkàn balẹ̀, kí ẹ kírun (ní pípé). Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ẹ má ṣe káàárẹ̀ nípa wíwá àwọn ènìyàn náà (láti jà wọ́n lógun). Tí ẹ̀yin bá ń jẹ ìrora (ọgbẹ́), dájúdájú àwọn náà ń jẹ ìrora (ọgbẹ́) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe ń jẹ ìrora rẹ̀. Ẹ̀yin sì ń retí ohun tí àwọn kò retí lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo nítorí kí o lè máa ṣèdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí Allāhu fi hàn ọ́. Má ṣe jẹ́ olùgbèjà fún àwọn oníjàǹbá.[1]
Tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu,[1] dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Má ṣe bá àwọn tó ń jàǹbá ẹ̀mí ara wọn wá àwíjàre. Dájúdájú Allāhu kò fẹ́ràn ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ oníjàǹbá, ẹlẹ́ṣẹ̀.[1]
Wọ́n ń fi ara pamọ́ fún àwọn ènìyàn, wọn kò sì lè fara pamọ́ fún Allāhu (nítorí pé) Ó wà pẹ̀lú wọn (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀) nígbà tí wọ́n ń pètepèrò lórí ohun tí (Allāhu) kò yọ́nú sí nínú ọ̀rọ̀ sísọ.[1] Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Kíyè sí i, ẹ̀yin wọ̀nyí ni ẹ̀ ń bá wọn mú àwíjàre wá nílé ayé. Ta ni ó máa bá wọn mú àwíjàre wá ní ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde? Tàbí ta ni ó máa jẹ́ aláàbò fún wọn?
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan tàbí tí ó ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, lẹ́yìn náà tí ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu, ó máa bá Allāhu ní Aláforíjìn, Aláàánú.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, ó dá a fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣìṣe kan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, ó dì í ru aláìmọwọ́-mẹsẹ̀, ó ti dá ọ̀ràn ìparọ́mọ́ni àti ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé.
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti gbèrò láti ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ẹ̀mí ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́;[1] oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun tó tóbi.
Kò sí oore kan nínú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn àfi ẹni tí ó bá pàṣẹ ọrẹ títa tàbí iṣẹ́ rere tàbí àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn láti fi wá ìyọ́nú Allāhu, láìpẹ́ A máa fún un ní ẹ̀san ńlá.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa Òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú han sí i kedere, tí ó tún tẹ̀lé ọ̀nà tó yàtọ̀ sí ti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, A óò dojú rẹ̀ kọ ohun tí ó dojú ara rẹ̀ kọ (nínú ìṣìnà),A sì máa mú un wọ inú iná Jahanamọ. Ó sì burú ní ìkángun.
Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Wọn kò pe kiní kan lẹ́yìn Allāhu bí kò ṣe àwọn abo òrìṣà.[1] Wọn kò sì pe kiní kan bí kò ṣe ṣaetọ̄n olùyapa.
Allāhu ṣẹ́bilé e. Ó sì wí pé: “Dájúdájú mo máa mú ìpín tí wọ́n pín fún mi nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ.
Dájúdájú mo máa ṣì wọ́n lọ́nà. Dájúdájú mo máa tàn wọ́n jẹ. Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa gé etí ẹran-ọ̀sìn (láti yà á sọ́tọ̀ fún òrìṣà). Dájúdájú mo máa pa wọ́n láṣẹ, wọn yó sì máa yí ẹ̀sìn Allāhu padà.”[1] Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú aṣ-Ṣaetọ̄n ní ọ̀rẹ́ lẹ́yìn Allāhu, dájúdájú ó ti ṣòfò ní òfò pọ́nńbélé.
Ó ń ṣàdéhùn fún wọn, ó sì ń tàn wọ́n jẹ. Aṣ-Ṣaetọ̄n kò sì ṣàdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn.
Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; wọn kò níí rí ibùsásí kan (wọn kò níí rí ọ̀nà láti sá jàde kúrò nínú rẹ̀).
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, A máa mú wọn wọ inu àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀ títí láéláé. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Ta sì ni ó sọ òdodo ju Allāhu?
Kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn onítírà (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.[1]
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ rere, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, onígbàgbọ́ òdodo sì ni, àwọn wọ̀nyẹn máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí fi (òdiwọ̀n) àmì ẹ̀yìn kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn.
Ta l’ó dára ní ẹ̀sìn ju ẹni tí ó jura rẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu, olùṣe-rere sì tún ni, ó tún tẹ̀lé ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-’Islām? Allāhu sì mú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní àyànfẹ́.
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa gbogbo n̄ǹkan.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìdájọ́ nípa àwọn obìnrin. Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ ìdájọ́ wọn fún yín. Ohun tí wọ́n ń ké fún yín nínú Tírà (al-Ƙur’ān náà ń sọ ìdájọ́ fún yín) nípa àwọn ọmọ-òrukàn lóbìnrin tí ẹ kì í fún ní ohun tí wọ́n kọ fún wọn (nínú ogún), tí ẹ tún ń ṣojú-kòkòrò pé ẹ fẹ́ fẹ́ wọn àti nípa àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọmọdé (tí ẹ̀ ń jẹ ogún wọn mọ́lẹ̀.) àti nípa pé kí ẹ dúró ti àwọn ọmọ òrukàn pẹ̀lú déédé. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe ní rere, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀.
Tí obìnrin kan bá páyà oríkunkun tàbí ìkẹ̀yìnsí láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì pé kí wọ́n ṣe àtúnṣe láààrin ara wọn. Àtúnṣe sì dára júlọ. Wọ́n sì ti fi ahun àti ọ̀kánjúà ṣíṣe sínú ẹ̀mí ènìyàn. Tí ẹ bá ṣe rere, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]
Ẹ kò lè ṣe déédé (nínú ìfẹ́) láààrin àwọn obìnrin, ẹ ò báà jẹ̀rankàn rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fì síbì kan tán pátápátá, kí ẹ wá pa (ẹnì kan) tì bí ohun tí wọ́n gbékọ́ ara ilé. Tí ẹ bá ṣàtúnṣe, tí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Tí àwọn méjèèjì bá sì pínyà, Allāhu yóò rọ ìkíní kejì lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀ tó gbòòrò. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbòòrò (nínú ọrọ̀), Ọlọ́gbọ́n.
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Dájúdájú A ti pa á láṣẹ fún àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín àti ẹ̀yin náa pé kí ẹ bẹ̀rù Allāhu. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn (tí ẹyìn tọ́ sí).
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.
Tí (Allāhu) bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò lórí ilẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn. Ó sì máa mú àwọn mìíràn wá. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí ìyẹn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ẹ̀san nílé ayé, ṣebí lọ́dọ̀ Allāhu ní ẹ̀san ti ayé àti ti ọ̀run wà. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Olùríran.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ olùdúró ṣinṣin lórí déédé nítorí ti Allāhu nígbà tí ẹ bá ń jẹ́rìí, kódà kí (ẹ̀rí jíjẹ́ náà) tako ẹ̀yin fúnra yín tàbí àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí; yálà ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí aláìní, Allāhu súnmọ́ (yín) ju àwọn méjèèjì. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú láti má ṣe déédé. Tí ẹ bá yí ojú-ọ̀rọ̀ sódì tàbí tí ẹ bá gbúnrí kúrò (níbi déédé), dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.[1]
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà tefétefé.
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n sì lékún sí i nínú àìgbàgbọ́, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fí ọ̀nà mọ̀ wọ́n.[1]
Fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìró pé dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn.
(Àwọn ni) àwọn tó ń mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ṣé ẹ̀ ń wá agbára lọ́dọ̀ wọn ni? Dájúdájú ti Allāhu ni gbogbo agbára pátápátá.
(Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú bí irú wọn ni ẹ̀yin náà. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ.
(Àwọn ni) àwọn tó fẹ́ yọ̀ yín; tí ìṣẹ́gun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu bá jẹ́ tiyín, wọ́n á wí pé: “Ṣé àwa kò wà pẹ̀lú yín bí?” Tí ìpín kan bá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, (àwọn mùnááfìkí) á wí pé: “Ṣé àwa kò ti ní ìkápá láti jẹ gàba le yín lórí (àmọ́ tí àwa kò ṣe bẹ́ẹ̀), ṣé àwa kò sì dáàbò bò yín tó lọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (títí ọwọ́ yín fi ba ọrọ̀-ogun, nítorí náà kí ni ìpín tiwa tí ẹ fẹ́ fún wa?)”[1] Nítorí náà, Allāhu yóò ṣèdájọ́ láààrin yín ní Ọjọ́ Àjíǹde. Allāhu kò sì níí fún àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀nà (ìṣẹ́gun) kan lórí àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀.
Wọ́n ń ṣe bàlàbàlà síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọn kò jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí, wọn kò sì jẹ́ ti àwọn wọ̀nyí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí ọ̀nà kan fún un.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn aláìgbàgbọ́ ní ọ̀rẹ́ àyò lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ yín). Ṣé ẹ fẹ́ ṣe n̄ǹkan tí Allāhu yóò fi ní ẹ̀rí pọ́nńbélé lọ́wọ́ láti jẹ yín níyà ni?
Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn.
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n dúró ṣinṣin ti Allāhu, tí wọ́n sì ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn wọn fún Allāhu. Nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn máa wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Láìpẹ́ Allāhu máa fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ẹ̀san ńlá.
Kí ni Allāhu máa fi jíjẹ yín níyà ṣe, tí ẹ bá dúpẹ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ ní òdodo? Allāhu sì ń jẹ́ Ọlọ́pẹ́,[1] Onímọ̀.
Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ sí ariwo ọ̀rọ̀ burúkú (láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni)[1] àyàfi ẹni tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí. Allāhu sì ń jẹ́ Olùgbọ́, Onímọ̀.
Tí ẹ bá ṣàfi hàn rere tàbí ẹ fi pamọ́ tàbí ẹ ṣàmójú kúrò níbi aburú, dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámòjúúkúrò, Alágbára.
Dájúdájú àwọn tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì fẹ́ máa ṣòpínyà láààrin Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú apá kan, a sì ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan,” wọ́n sì fẹ́ mú ọ̀nà kan tọ̀ (lẹ́sìn) láààrin ìyẹn.
Ní òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni aláìgbàgbọ́. A sì ti pèsè Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí wọn kò sì ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn, láìpẹ́ àwọn wọ̀nyẹn, (Allāhu) máa fún wọn ní ẹ̀san wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Àwọn onítírà ń bi ọ́ léèrè pé kí o sọ tírà kan kalẹ̀ láti inú sánmọ̀. Wọ́n kúkú bi (Ànábì) Mūsā ní ohun tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Wọ́n wí pé: “Fi Allāhu hàn wá ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá wọn mú nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún sọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di n̄ǹkan tí wọ́n jọ́sìn fún lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. A tún ṣàmójú kúrò níbi ìyẹn. A sì fún (Ànábì) Mūsā ní ẹ̀rí pọ́nńbélé.
A gbé àpáta sókè orí wọn nítorí májẹ̀mu wọn. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà ìlú wọlé ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún.” A tún sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà ní ọjọ́ Sabt.” A sì gba àdéhùn tó nípọn lọ́wọ́ wọn.
Nítorí yíyẹ̀ tí wọ́n fúnra wọn yẹ àdéhùn wọn, àti ṣíṣàìgbàgbọ́ wọn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu, àti pípa tí wọ́n ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́ àti wíwí tí wọ́n ń wí pé: “Ọkàn wa ti di.” - rárá, Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn ni nítorí àìgbàgbọ́ wọn. - Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn).
Àti nítorí àìgbàgbọ́ wọn àti ọ̀rọ̀ wọn lórí Mọryam ní ti ìbànilórúkọjẹ́ ńlá (Allāhu tún fi èdídí dí ọkàn wọn).
Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.[1] Dájúdájú àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì lórí rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé àbá dídá. Wọn kò pa á ní ti àmọ̀dájú.
bí kò ṣe pé Allāhu gbé e wá sókè lọ́dọ̀ Rẹ̀ ni. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.[1]
Kò sì níí sí ẹnì kan nínú àwọn onítírà (láyé nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam bá sọ̀kalẹ̀ padà láti ojú sánmọ̀) àfi kí ó gbà á gbọ́ ní òdodo ṣíwájú ikú rẹ̀.[1]Ní Ọjọ́ Àjíǹde, ó sì máa jẹ́ ẹlẹ́rìí lórí wọn.
Nítorí àbòsí láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n di yẹhudi, A ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa kan ní èèwọ̀ fún wọn, èyí tí wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn (tẹ́lẹ̀. A ṣe é ní èèwọ̀ fún wọn sẹ́) nípa bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu.
Àti gbígbà tí wọ́n ń gba owó èlé, tí A sì ti kọ̀ ọ́ fún wọn, àti jíjẹ tí wọ́n ń jẹ dúkìá àwọn ènìyàn lọ́nà èrú. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Ṣùgbọ́n àwọn tó jindò nínú ìmọ̀ nínú wọn àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, wọ́n gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ, àwọn tó ń kírun àtí àwọn tó ń yọ Zakāh àti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn wọ̀nyẹn ni A máa fún ní ẹ̀san ńlá.
Dájúdájú Àwa (fi ìmísí) ránṣẹ́ sí ọ gẹ́gẹ́ bí A ṣe fi ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh àti àwọn Ànábì (mìíràn) lẹ́yìn rẹ̀. A fi ìmísí ránṣẹ́ sí (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ (rẹ̀), àti (Ànábì) ‘Īsā, ’Ayyūb, Yūnus, Hārūn àti Sulaemọ̄n. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr.
Àti àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A ti sọ ìtàn wọn fún ọ ṣíwájú pẹ̀lú àwọn Òjíṣẹ́ kan tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ. Allāhu sì bá (Ànábì) Mūsā sọ̀rọ̀ tààrà.
(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́). Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ṣùgbọ́n Allāhu ń jẹ́rìí sí ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. Àwọn mọlāika náà ń jẹ́rìí (sí i). Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, wọ́n kúkú ti ṣìnà ní ìṣìnà tó jìnnà.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣàbòsí, Allāhu kò níí forí jìn wọ́n, kò sì níí fi ojú-ọ̀nà kan mọ̀ wọ́n.
Àyàfi ojú-ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.[1]
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Òjíṣẹ́ náà ti dé ba yín pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kí ẹ gbà á gbọ́ l’ó dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Ó fi dá Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fún yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.[1]
Mọsīh kò kọ̀ láti jẹ́ ẹrú fún Allāhu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn mọlāika tí wọ́n súnmọ́ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti jọ́sìn fún Un, tí ó tún ṣègbéraga, (Allāhu) yóò kó wọn jọ papọ̀ pátápátá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ó sì máa ṣe àlékún fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Ní ti àwọn tó bá sì kọ̀ (láti jọ́sìn fún Allāhu), tí wọ́n sì ṣègbéraga, (Allāhu) yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro. Wọn kò sì níí rí alátìlẹ́yìn tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. A sì tún sọ ìmọ́lẹ̀ tó yanjú kalẹ̀ fún yín.
Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, tí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì Í, Ó máa fi wọ́n sínú ìkẹ́ àti ọlá kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa fi wọ́n mọ ọ̀nà tààrà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fún yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ ará (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fún yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.