عربيEnglish

The Noble Qur'an Encyclopedia

Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languages

The Table Spread [Al-Maeda] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 107

Surah The Table Spread [Al-Maeda] Ayah 120 Location Madanah Number 5

فَإِنۡ عُثِرَ عَلَىٰٓ أَنَّهُمَا ٱسۡتَحَقَّآ إِثۡمٗا فَـَٔاخَرَانِ يَقُومَانِ مَقَامَهُمَا مِنَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَوۡلَيَٰنِ فَيُقۡسِمَانِ بِٱللَّهِ لَشَهَٰدَتُنَآ أَحَقُّ مِن شَهَٰدَتِهِمَا وَمَا ٱعۡتَدَيۡنَآ إِنَّآ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ [١٠٧]

Tí wọ́n bá sì mọ̀ pé àwọn méjèèjì dá ẹ̀ṣẹ̀ (nípa yíyí àsọọ́lẹ̀ padà tàbí jíjí dúkìá aláìsí), kí àwọn méjì mìíràn nínú ẹbí òkú tí àsọọ́lẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ sì jùlọ,[1] (ìyẹn) ènìyàn méjì tí ó súnmọ́ òkú jùlọ rọ́pò àwọn méjèèjì àkọ́kọ́ (níbi mímú àsọọ́lẹ̀ mìíràn wá fún òkú). Kí àwọn náà sì fi Allāhu búra pé: “Dájúdájú ẹ̀rí jíjẹ́ tiwa jẹ́ òdodo ju ẹ̀rí jíjẹ́ ti àwọn méjèèjì (àkọ́kọ́). A ò sì níí tayọ ẹnu-ààlà. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) nígbà náà, dájúdájú a ti wà nínú àwọn alábòsí.”