The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Table Spread [Al-Maeda] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 4
Surah The Table Spread [Al-Maeda] Ayah 120 Location Madanah Number 5
يَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَآ أُحِلَّ لَهُمۡۖ قُلۡ أُحِلَّ لَكُمُ ٱلطَّيِّبَٰتُ وَمَا عَلَّمۡتُم مِّنَ ٱلۡجَوَارِحِ مُكَلِّبِينَ تُعَلِّمُونَهُنَّ مِمَّا عَلَّمَكُمُ ٱللَّهُۖ فَكُلُواْ مِمَّآ أَمۡسَكۡنَ عَلَيۡكُمۡ وَٱذۡكُرُواْ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهِۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ [٤]
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè pé: “Kí ni wọ́n ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn?” Sọ pé: “Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún yín àti (ẹran tí ẹ pa nípasẹ̀) èyí tí ẹ kọ́ ní ẹ̀kọ́ (ìdọdẹ) nínú àwọn ẹranko àti ẹyẹ tí ń dọdẹ. Ẹ kọ́ àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ ìdọdẹ, kí ẹ kọ́ wọn nínú ohun tí Allāhu fi mọ̀ yín. Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá pa fún yín, kí ẹ sì ṣe bismillāh sí i[1]. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.