عربيEnglish

The Noble Qur'an Encyclopedia

Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languages

The cattle [Al-Anaam] - Yoruba translation

Surah The cattle [Al-Anaam] Ayah 165 Location Maccah Number 6

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,[1] Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó tún dá òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.

Òun ni Ẹni tí Ó da yín láti inú ẹrẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó fi gbèdéke àkókó kan sí (ìṣẹ̀mí ayé yín). Àti pé gbèdéke àkókò kan (tún wà fún ayé) lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣeyèméjì.

Òun ni Allāhu (Ẹni tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ó mọ ìkọ̀kọ̀ yín àti gban̄gba yín. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Kò sí āyah kan (àti àmì kan) tí ó máa dé bá wọn nínú àwọn āyah (àti àmì) Olúwa wọn, àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

Wọ́n kúkú pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, láìpẹ́ àwọn ìró ohun tí wọ́n máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.

Ṣé wọn kò wòye pé ó pọ̀ nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn.

Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: “Èyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?” Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́.

Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú.[1]

Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.

Sọ pé: “Ẹ rin orí ilẹ̀ lọ, lẹ́yìn náà kí ẹ wo báwo ni àtubọ̀tán àwọn tó ń pe òdodo nírọ́ ṣe rí.”

Sọ pé: “Ti ta ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni.” Ó ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí.[1] Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò níí gbàgbọ́.

TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó ń bẹ nínú òru àti ọ̀sán. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).”[1] Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ Ńlá, tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”

Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá darí rẹ̀ kúrò níbi (ìyà) ní Ọjọ́ yẹn, (Allāhu) ti ṣàánú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé.

Tí Allāhu bá fi ìnira kan kàn ọ́, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun náà. Tí Ó bá sì mú oore kan bá ọ, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

Òun sì ni Olùborí tó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.[1]

Sọ pé: “Kí ni ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀rí?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin.” Ó sì fi ìmísí al-Ƙur’ān yìí ránṣẹ́ sí mi, nítorí kí n̄g lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin àti ẹnikẹ́ni tí (al-Ƙur’ān) bá dé etí ìgbọ́ rẹ̀.[1] Ṣé dájúdájú ẹ̀yin ń jẹ́rìí pé àwọn ọlọ́hun mìíràn tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.” Sọ pé: “Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àti pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).”

Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́.[1]

Ta l’ó sì ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí (ẹni tí) ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.

Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn tó bá (Allāhu) wá akẹgbẹ́ pé: “Níbo ni àwọn òrìṣà yín wà, àwọn tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Allāhu?”

Lẹ́yìn náà, ìfòòró wọn (lórí ìbéèrè náà) kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n á wí pé: “A fi Allāhu Olúwa wa búra, àwa kì í ṣe ọ̀ṣẹbọ.”

Wo bí wọ́n ṣe parọ́ mọ́ra wọn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1]

Ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ ń bẹ nínú wọn. A sì fi èbìbò bo ọkàn wọn kí wọ́n má baà gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Tí wọ́n bá rí gbogbo āyah (àmì), wọn kò níí gbà á gbọ́ débi pé nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ, wọn yó sì máa bá ọ jiyàn; àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì máa wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

Àwọn ni wọ́n ń kọ̀ (fún àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.), àwọn náà sì ń takété sí i. Wọn kò sì kó ìparun bá ẹnikẹ́ni bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.

Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró síbi Iná, wọ́n sì máa wí pé: “Yéè! Kí ó sì jẹ́ pé wọ́n dá wa padà (sílé ayé), àwa kò sì níí pe àwọn āyah Olúwa wa nírọ́ (mọ́), a sì máa wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

Kò rí bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ láti ẹ̀yìn wá ti hàn sí wọn ni. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.

Wọ́n wí pé: ““Kò sí (ohun tó ń jẹ́ ìṣẹ̀mí ọ̀run) bí kò ṣe ìṣẹ̀mí wa nílé ayé; Wọn kò sì níí gbé wa dìde (ní ọ̀run).”

Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, Ó sì máa sọ pé: “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọ́n á sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (òdodo ni), Olúwa wa.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ máa ń ṣàì gbàgbọ́.”

Dájúdájú àwọn tó pe pípàdé Allāhu (lọ́run) nírọ́ ti ṣòfò débi pé nígbà tí Àkókò náà bá dé bá wọn lójijì, wọ́n á wí pé: “A ká àbámọ̀ lórí ohun tí a fi jáfira nílé ayé.” Wọ́n sì máa ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn sẹ́yìn wọn. Kíyè sí i, ohun tí wọn yóò rù lẹ́ṣẹ̀ sì burú.

Ìṣẹ̀mí ayé kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe eré àti ìranù. Ọgbà Ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

A kúkú ti mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń wí ń bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú wọn kò lè pè ọ́ ní òpùrọ́, ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ń tako àwọn āyah Allāhu ni.

Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu.[1] Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ.

Tí ó bá sì jẹ́ pé gbígbúnrí wọn lágbára lára rẹ, nígbà náà tí o bá lágbára láti wá ihò kan sínú (àjà) ilẹ̀, tàbí àkàbà kan sínú sánmọ̀ (ṣe bẹ́ẹ̀) kí o lè mú àmì kan wá fún wọn. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá kó wọn jọ papọ̀ sínú ìmọ̀nà(’Islām). Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn aláìmọ̀kan.

Ọ̀wọ́ ẹni tó ń jẹ́pè ni àwọn tó ń gbọ́rọ̀. (Ní ti) àwọn òkú, Allāhu yó gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí.

Wọ́n tún wí pé: “Nítorí kí ni wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.”

Kò sí ohun abẹ̀mí kan (tó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan tó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí.

Àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́, adití àti ayaya tó wà nínú àwọn òkùnkùn ni wọ́n. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa ṣì í lọ́nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fi sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín tàbí tí Àkókò náà bá dé ba yín, ṣe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni ẹ̀yin máa pè, tí ẹ bá jẹ́ olódodo!”

Rárá o, Òun (nìkan) lẹ máa pè. Ó sì máa mú (ìnira) tí ẹ̀ ń pè É sí kúrò (fún yín) tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin yó sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ sí I.

Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi àwọn ìpọ́njú àti àwọn àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).[1]

Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn le koko. Aṣ-Ṣaetọ̄n sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn.

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù.

Nítorí náà, A pa ìjọ tó ṣàbòsí run pátápátá. Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoso, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.[1]

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá gba ìgbọ́rọ̀ yín àti ìríran yín, tí Ó sì di ọkàn yín pa, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu ni ó máa mú un wá fún yín? Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo)!

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín ní òjijì tàbí ní gban̄gba ojúkojú, ṣé wọ́n máa pa ẹnì kan run bí kò ṣe ìjọ alábòsí!”

A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí wọ́n jẹ́) oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ rẹ̀), kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́.

Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, ọwọ́ ìyà yóò tẹ̀ wọ́n nítorí pé wọ́n máa ń yapa àṣẹ (Allāhu).

Sọ pé: “Èmi kò sọ fún yín pé àwọn ilé-ọrọ̀ Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fún yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí.” Sọ pé: “Ǹjẹ́ afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí?[1] Ṣé ẹ ò ronú jinlẹ̀ ni?”

Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń páyà pé wọ́n máa kó àwọn jọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, kò sì níí sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.[1] (Kìlọ̀ fún wọn) kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.[1]

Báyẹn ni A ṣe fi apá kan wọn ṣe àdánwò fún apá kan nítorí kí (àwọn aláìgbàgbọ́) lè wí pé: “Ṣé àwọn (mùsùlùmí aláìní) wọ̀nyí náà ni Allāhu ṣe ìdẹ̀ra (ìmọ̀nà) fún láààrin wa!?” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùdúpẹ́ ni?

Nígbà tí àwọn tó gba àwọn āyah Wa gbọ́ bá wá bá ọ, sọ (fún wọn) pé: “Kí àlàáfíà máa ba yín. Olúwa yín ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí ó ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”[1]

Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà nítorí kí ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fojú hàn kedere.

Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi láti jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu.” Sọ pé: “Èmi kò níí tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, mo ti ṣìnà, èmi kò sì sí nínú àwọn olùmọ̀nà (tí mo bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín).”

Sọ pé: “Dájúdájú mo wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, ẹ̀yin sì pè é nírọ́. Kò sí ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ní ọ̀dọ̀ mi. Kò sí ìdájọ́ náà (fún ẹnikẹ́ni) àyàfi fún Allāhu, Ẹni tí ń sọ (ìdájọ́) òdodo. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”[1]

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi ni, Wọn ìbá ti ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà láààrin èmi àti ẹ̀yin. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn alábòsí.”

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni tó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.

Òun ni Ẹni tó ń kùn yín ní oorun ní alẹ́.[1] Ó sì nímọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́ ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbe yín dìde (fún ìjẹ-ìmu) ní (ọ̀sán) nítorí kí wọ́n lè parí gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí yín. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Òun ni Olùborí tó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀.[1] Ó sì ń rán àwọn ẹ̀ṣọ́ kan (nínú àwọn mọlāikah) si yín títí di ìgbà tí ikú yóò fi dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Àwọn Òjíṣẹ́ wa yó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, wọn kò sì níí jáfira.

Lẹ́yìn náà, wọ́n yóò dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu Olúwa wọn Òdodo. Kíyè sí i, tiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ó sì yára jùlọ nínú àwọn olùṣírò.[1]

Sọ pé: “Ta ni ẹni tó ń gbà yín là nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò, Ẹni tí ẹ̀ ń pè pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ní ìkọ̀kọ̀ pé: “Dájúdájú tí Ó bá gbà wá là nínú èyí, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un)?”

Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń gbà yín là nínú rẹ̀ àti nínú gbogbo ìbànújẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣẹbọ.”

Sọ pé: “Ó lágbára láti fi ìyà ránṣẹ́ si yín láti òkè yín tàbí láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ yín, tàbí kí Ó dà yín pọ̀ mọ́ onírúurú ìjọ, nítorí kí Ó lè mu apá kan yín fìnira kan apá kan. Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè gbọ́ àgbọ́yé.”

Àwọn ènìyàn rẹ pe al-Ƙur’ān nírọ́! (Àmọ́) òdodo ni. Sọ pé: “Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.”

Gbogbo ìró (àsọtẹ́lẹ̀) l’ó máa wá sí ìmúṣẹ. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

Nígbà tí o bá rí àwọn tó ń sọ ìsọkúsọ nípa àwọn āyah Wa, nígbà náà ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn. Tí aṣ-Ṣaetọ̄n bá ń mú ọ gbàgbé (tẹ́lẹ̀), ní báyìí lẹ́yìn ìrántí má ṣe jókòó ti ìjọ alábòsí.

Kiní kan nínú ìṣírò-iṣẹ́ wọn kò sí lọ́rùn àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ìṣítí ni nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

Pa àwọn tó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi al-Ƙur’ān ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.[1] Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́.

Sọ pé: “Ṣé a óò máa pè lẹ́yìn Allāhu, ohun tí kò lè ṣe wá ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wa; (ṣé) kí wọ́n tún dá wa padà sí ẹsẹ̀-àárọ̀ wa lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti fi ọ̀nà mọ̀ wá (kí á lè dà) bí ẹni tí àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n tàn lọ (sínú igbó), ó sì ń dààmú kiri lórí ilẹ̀, ó sì kúkú ní àwọn ọ̀rẹ́ (alábàárìn) kan tí wọ́n ń pè é sí ọ̀nà (ilé) pé, “Máa bọ̀ wá bá wa.” (àmọ́ kò gbọ́ mọ́). Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà ti Allāhu (’Islām), òhun ni ìmọ̀nà. Wọ́n sì pa wá láṣẹ pé kí á gba ẹ̀sìn ’Islām nítorí ti Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

Àti pé kí ẹ kírun, kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Òun ni Ẹni tí wọ́n yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu máa yí ilẹ̀ àti sánmọ̀ padà sí n̄ǹkan mìíràn)[1], Ó sì máa sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Òdodo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀. TiRẹ̀ ni ìjọba ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba ni. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.

(Rántí) nígbà tí ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ Āzar (pé): “Ṣé o máa sọ àwọn ère òrìṣà di ọlọ́hun ni? Dájúdájú èmi rí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú.

Nígbà tí òkùnkùn alẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó rí ìràwọ̀ kan, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn (olúwa) tó ń wọ̀ọ̀kùn.”

Nígbà tí ó rí òṣùpá tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Dájúdájú tí Olúwa mi kò bá tọ́ mi sọ́nà, dájúdájú mo máa wà nínú àwọn olùṣìnà ènìyàn.”

Nígbà tí ó rí òòrùn tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà tó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).[1]

Dájúdájú èmi dojú mi kọ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (mo) dúró déédé (sínú ’Islām fún Un). Èmi kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

Àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jà á níyàn. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò jà mí níyàn nípa Allāhu, Ó sì ti fi ọ̀nà mọ̀ mí? Èmi kò sì páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Un, àfi bí Allāhu bá fẹ́ kiní kan (pé kó ṣẹlẹ̀). Olúwa mi fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

Báwo ni èmi yóò ṣe páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Allāhu, tí ẹ̀yin kò sì páyà pé ẹ̀ ń bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pẹ̀lú ohun tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún yín lórí rẹ̀? Èwo nínú ikọ̀ méjèèjì l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ẹ bá nímọ̀?

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọn kò sì da ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ mọ́ àbòsí (ìbọ̀rìṣà), àwọn wọ̀nyẹn ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ń bẹ fún. Àwọn sì ni olùmọ̀nà.

Ìyẹn ni àwíjàre Wa tí A fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. À ń ṣe àgbéga ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Àti pé A ta á lọ́rẹ (Ànábì) ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (tí ó jẹ́ ọmọ ’Ishāƙ). Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fi mọ̀nà. A sì fi (Ànábì) Nūh mọ̀nà ṣíwájú. Àti pé nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì ’Ibrọ̄hīm tí A fi mọ̀nà ni àwọn Ànábì) Dāwūd, Sulaemọ̄n, ’Ayyūb, Yūsuf, Mūsā àti Hārūn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

Àti (Ànábì) Zakariyyā, Yahyā, ‘Īsā àti ’Ilyās; gbogbo wọn wà nínú àwọn ẹni rere.

Àti ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘, Yūnus àti Lūt; ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A ṣoore àjùlọ fún lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn).

Àti pé nínú àwọn bàbá wọn, àrọ́mọdọ́mọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn, A tún ṣà wọ́n lẹ́ṣà. A sì fi wọ́n mọ̀nà tààrà (’Islām).

Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà nínú àwọn ẹrú Rẹ̀. Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A fún ní Tírà, òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) àti (ipò) Ànábì. Nítorí náà, tí àwọn wọ̀nyí bá ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú A ti gbé e lé àwọn ènìyàn kan lọ́wọ́, tí wọn kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Nítorí náà, ọ̀nà wọn ni kí o tẹ̀lé. Sọ pé: “Èmi kò bi yín ní owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.”

Wọn kò fún Allāhu ní iyì tí ó tọ́ sí I, nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀ fún abara kan.” Sọ pé: “Ta ni Ó sọ tírà tí (Ànábì) Mūsā mú wá kalẹ̀, (èyí tó jẹ́) ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn, èyí tí ẹ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé àjákọ, tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀, tí ẹ sì ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ rẹ̀ pamọ́, A sì fi ohun tí ẹ ò mọ̀ mọ̀ yín, ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Lẹ́yìn náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìsọkúsọ wọn, kí wọ́n máa ṣeré.

Èyí (al-Ƙur’ān) tún ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀; ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀ àti pé nítorí kí o lè ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù). Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, wọ́n gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn sì ni wọ́n ń ṣọ́ ìrun wọn.

Kò sí ẹni tó ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí ẹni tí ó wí pé wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi - A ò sì fi kiní kan ránṣẹ́ sí i - àti ẹni tí ó wí pé “Èmi náà yóò sọ irú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ kalẹ̀.”? Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé) “Ẹ mú ẹ̀mí yín jáde wá. Lónìí ni Wọn yóò san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí ohun tí ẹ̀ máa ń sọ nípa Allāhu ní ọ̀nà àìtọ́. Ẹ sì máa ń ṣe ìgbéraga sí àwọn āyah Rẹ̀.”

Dájúdájú ẹ ti wá bá wa ní ìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ẹ sì ti fi ohun tí A fún yín (nínú ọrọ̀ ayé) sílẹ̀ sí ẹ̀yìn yín. A ò mà rí àwọn olùṣìpẹ̀ yín pẹ̀lú yín, àwọn tí ẹ sọ láì ní ẹ̀rí pé dájúdájú láààrin yín àwọn ni akẹgbẹ́ (fún Allāhu). Dájúdájú àṣepọ̀ ààrin yín ti já pátápátá. Àti pé ohun tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn (láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí ìṣìpẹ̀ wọn) sì di òfo mọ yín lọ́wọ́.[1]

Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú kóró èso irúgbìn àti kóró èso dàbínù hù jáde. Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú. Ó sì ń mú òkú jáde láti ara alààyè. Ìyẹn ni Allāhu. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

Ó ń mú ojúmọ́ mọ́. Ó ṣe òru ní ìsinmi. (Ó ń mú) òòrùn àti òṣùpá (rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.

Òun ni Ẹni tí Ó fi àwọn ìràwọ̀ ṣe (ìmọ́lẹ̀) fún yín kí ẹ lè fi mọ̀nà nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn tó nímọ̀.

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Nítorí náà, ibùgbé (nílé ayé) àti ibùpadàsí (ní ọ̀run wà fún yín). A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn tó ní àgbọ́yé.

Òun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A fi mú gbogbo n̄ǹkan ọ̀gbìn jáde. A tún mú ewéko tó ń dán lọ̀gbọ́lọ̀gbọ́ jáde láti inú rẹ̀. A tún ń mú ṣiri èso jáde láti inú rẹ̀. (A sì ń mú jáde) láti ara igi dàbínù, láti ara èso àkọ́yọ rẹ̀, èso tó ṣùjọ mọ́ra wọn tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ wálẹ̀. (À ń ṣe) àwọn ọgbà oko èso àjàrà, èso zaetūn àti èso rummọ̄n (ní àwọn èso tó) jọra àti (àwọn èyí tí) kò jọra. Ẹ wo èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so àti (nígbà tí ó bá) pọ́n. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

Wọ́n sì fi àwọn àlùjànnú ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dàá wọn! Wọ́n tún parọ́ mọ́ Ọn (pé) Ó bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, láì nímọ̀ kan (nípa rẹ̀). Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni. Báwo ni Ó ṣe ní ọmọ nígbà tí kò ní aya. Ó dá gbogbo n̄ǹkan ni. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

Àwọn ojú (ẹ̀dá) kò lè ká Allāhu. Òun sì ká àwọn ojú. Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

Ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ríran, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fọ́jú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.

Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. - Kí wọ́n máa sọ pé, “O kẹ́kọ̀ọ́ (rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onítírà ni.” Dípò kí wọ́n wí pé: “Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ ni.”[1] - (A mú un wá lóníran-ànran ọ̀nà sẹ́) nítorí kí A lè ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn tó nímọ̀.

Tẹ̀lé ohun tí wọ́n fi rán ọ́ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.

Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ìmọ̀nà fún wọn), wọn ìbá tí ṣẹbọ. A ò sì fi ọ́ ṣe olùṣọ́ lórí wọn. Àti pé ìwọ kọ́ ni alámòjúútó wọn.

Ẹ má ṣe bú àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kí àwọn (abọ̀rìṣà) má baà bú Allāhu ní ti àbòsí àti àìnímọ̀. Báyẹn ni A ti ṣe iṣẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni ibùpadàsí wọn. Nítorí náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n máa ń ṣe níṣẹ́.

Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú tí àmì (ìyanu) kan bá dé bá àwọn, àwọn gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà.” Kí sì ni ó máa mu yín fura mọ̀ pé dájúdájú nígbà tí ó bá dé (bá wọn) wọn kò níí gbà á gbọ́?

A máa yí ọkàn wọn àti ojú wọn sódì ni (wọn kò sì níí gbà á gbọ́) gẹ́gẹ́ bí wọn kò ṣe gbàgbọ́ nínú (èyí tó ṣíwájú nínú àwọn àmì ìyanu) nígbà àkọ́kọ́. A ó sì fí wọn sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.

Dájúdájú tí A bá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wọn, tí àwọn òkú ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí A tún kó gbogbo n̄ǹkan jọ síwájú wọn, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi tí Allāhu bá fẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni aláìmọ̀kan.

Báyẹn ni A ti ṣe àwọn ṣaetọ̄n ènìyàn àti ṣaetọ̄n àlùjànnú ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan; apá kan wọn ń fi ọ̀rọ̀ dídùn (odù irọ́) ránṣẹ́ sí apá kan ní ti ẹ̀tàn. Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́ (láti tọ́ wọn sọ́nà ni) wọn ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, fi wọn sílẹ̀ tòhun ti àdápa irọ́ tí wọ́n ń dá.

Kí àwọn ọkàn àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí (odù irọ́ aṣ-Ṣaetọ̄n), kí wọ́n yọ́nú sí i, kí wọ́n sì máa dá ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀ ǹ só.

Ṣé n̄ǹkan mìíràn ni kí n̄g wá ní olùdájọ́ lẹ́yìn Allāhu ni? Òun sì ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún yín tí wọ́n fi ṣàlàyé ìdájọ́.[1] Àwọn tí A sì fún ní tírà mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ pé ní òdodo àti ní déédé. Kò sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Tí o bá tẹ̀lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀, wọ́n máa ṣì ọ́ lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọn kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Kí sì ni wọn (ń ṣe) bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Àti pé, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.

Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá fi orúkọ Allāhu pa, tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Rẹ̀.

Kí ni ó máa kọ̀ fún yín láti jẹ nínú ohun tí wọ́n fi orúkọ Allāhu pa! Ó kúkú ti ṣàlàyé fún yín ohun tí Ó ṣe ní èèwọ̀ fún yín àyàfi èyí tí wọ́n bá fi ìnira tì yín débẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni wọ́n ń fi ìfẹ́-inú wọn pẹ̀lú àìnímọ̀ (wọn) ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.

Ẹ fi èyí tó hàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti èyí tó pamọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀.

Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa.[1] Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Àti pé dájúdájú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.

Ǹjẹ́ ẹni tí (àfiwé rẹ̀) jẹ́ òkú (ìyẹn, aláìgbàgbọ́), tí A sọ di alààyè (nípa pé ó gba ’Islām), tí A sì fún un ní ìmọ́lẹ̀ (ìyẹn, ìmọ̀ ẹ̀sìn), tí ó sì ń lò ó láààrin àwọn ènìyàn, (ǹjẹ́) ó dà bí ẹni tí àfiwé tirẹ̀ jẹ́ (ẹni tí) ń bẹ nínú àwọn òkùnkùn (àìgbàgbọ́), tí kò sì jáde kúrò nínú rẹ̀? Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Báyẹn ni A ṣe sọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú[1] kan di ọ̀daràn ìlú nínú ìlú kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè máa dète níbẹ̀. Wọn kò sì dète sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí ara wọn, wọn kò sì fura.

Nígbà tí āyah kan bá sì dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Àwa kò níí gbà á gbọ́ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fún àwa náà ní irú ohun tí wọ́n fún àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu.” Allāhu ló nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí.[1] Láìpẹ́ ìyẹpẹrẹ àti ìyà líle láti ọ̀dọ̀ Allāhu yóò dé bá àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n ń dá léte.

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fọ̀nà mọ̀, Ó máa ṣí igbá-àyà rẹ̀ payá fún ’Islām. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́ ṣì lọ́nà, Ó máa fún igbá-àyà rẹ̀ pa gádígádí bí ẹni pé ó la ìgùnkè lọ sínú sánmọ̀ bọra rẹ̀ lọ́rùn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ṣe ìyà fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

Èyí ni ojú ọ̀nà Olúwa rẹ (tó jẹ́) ọ̀nà tààrà. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń lo ìrántí.

Ilé àlàáfíà ń bẹ fun wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Òun sì ni Alátìlẹ́yìn wọn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

(Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́[1]. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Báyẹn ni A ṣe fi apá kan àwọn alábòsí ṣọ̀rẹ́ apá kan (wọn) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, ṣé àwọn Òjíṣẹ́ kan láààrin yín kò wá ba yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Mi fún yín, tí wọ́n sì ń fi ìpàdé yín Òní yìí ṣèkìlọ̀ fún yín? Wọ́n wí pé: “A jẹ́rìí léra wa lórí (pé wọ́n wá).” Ìṣẹ́mí ayé tàn wọ́n jẹ. Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé, dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.

Ìyẹn nítorí pé, Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run nípasẹ̀ àbòsí (ọwọ́ wọn), lásìkò tí àwọn ara ìlú náà jẹ́ aláìmọ̀ (títí Òjíṣẹ́ yóò fi dé bá wọn).

Àwọn ipò (ìkẹ́ àti ipò ìyà) ń bẹ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ohun tí wọ́n bá ṣe níṣẹ́. Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Olúwa rẹ ni Ọlọ́rọ̀, Aláàánú. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò (lórí ilẹ̀). Ó sì máa fi ohun tí Ó bá fẹ́ rọ́pò (yín) lẹ́yìn (ìparun) yín gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe mu yín jáde lẹ́yìn (ìparun) àrọ́mọdọ́mọ àwọn ìjọ mìíràn.

Dájúdájú ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín, ó kúkú ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀; ẹ̀yin kò sì lè dá Allāhu lágara.[1]

Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣisẹ́ ní àyè yín. Dájúdájú èmi náà ń ṣiṣẹ́.[1] Láìpẹ́ ẹ̀ máa mọ ẹni tí Ilé Ìkángun-rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

Wọ́n sì fi ìpín kan fún Allāhu nínú ohun tí Ó dá nínú n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn; wọ́n wí pé: “Èyí ni ti Allāhu - pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, - èyí sì ni ti àwọn òrìṣà wa.” Nítorí náà, ohun tí ó bá jẹ́ ti àwọn òrìṣà kò níí dàpọ̀ mọ́ ti Allāhu. Ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Allāhu, ó ń dàpọ̀ mọ́ ti àwọn òrìṣà wọn; ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.

Báyẹn ni àwọn òrìṣà wọn ṣe pípa àwọn ọmọ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ nítorí kí wọ́n lè pa wọ́n run àti nítorí kí wọ́n lè d’ojú ẹ̀sìn wọn rú mọ́ wọn lọ́wọ́. Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí ṣe (bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ tòhun ti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.

Wọ́n tún wí pé: “Èèwọ̀ ni àwọn ẹran-ọ̀sìn àti n̄ǹkan oko wọ̀nyí. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi ẹni tí a bá fẹ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́.” - Àwọn ẹran-ọ̀sìn kan tún ń bẹ tí wọ́n ṣe ẹ̀yìn wọn ní èèwọ̀ (fún gígùn àti ẹrù rírù), àwọn ẹran kan tún ń bẹ tí wọn kì í fi orúkọ Allāhu pa. (Wọ́n fi àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí) dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.

Wọ́n tún wí pé: “Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa.” Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀.[1] (Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Àwọn tó fi agọ̀ àti àìmọ̀ pa àwọn ọmọ wọn kúkú ti ṣòfò; wọ́n tún ṣe ohun tí Allāhu pa lésè fún wọn ní èèwọ̀, ní ti dídá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Wọ́n kúkú ti ṣìnà, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn (n̄ǹkan) ọgbà oko èyí tí ẹ̀ ń fọwọ́ ara yín gbìn àti èyí tó ń lalẹ̀ hù àti dàbínù àti irúgbìn tí (adùn) jíjẹ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àti èso zaetūn àti èso rummọ̄n tó jọra wọn àti èyí tí kò jọra wọn. Ẹ jẹ nínú èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so, kí ẹ sì yọ Zakāh rẹ̀ ní ọjọ́ ìkórè rẹ̀. Kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.

Ó sì ń bẹ nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn, èyí tó lè ru ẹrù àti èyí tí kò lè ru ẹrù. Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n;[1] dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

(Allāhu dá ẹran) mẹ́jọ ní takọ- tabo; méjì nínú àgùtàn (takọ-tabo), méjì nínú ewúrẹ́ (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Ẹ fún mi ní ìró pẹ̀lú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

Méjì nínú ràkúnmí (takọ-tabo) àti méjì nínú màálù (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Tàbí ṣé ẹ̀yin wà níbẹ̀ nígbà tí Allāhu pa yín láṣẹ èyí ni?” Nítorí náà, kò sí ẹni tó ṣàbòsí tó ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

Sọ pé: “Èmi kò rí nínú ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi (n̄ǹkan kan ) tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran (yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà)[1], tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú pípe orúkọ mìíràn lé e lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Nítorí náà, ẹni tí ìnira (ebi) bá mú, yàtọ̀ sí ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà,² dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.³

A ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi gbogbo ẹran tó ní ọmọníka tó ṣùpọ̀ mọ́ra wọn. Nínú ẹran màálù àti àgùtàn, A tún ṣe ọ̀rá àwọn méjèèjì ní èèwọ̀ fún wọn àfi èyí tí ó bá lẹ̀mọ́ ẹ̀yìn wọn tàbí ìfun tàbí èyí tí ó bá yípọ̀ mọ́ eegun. Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Dájúdájú Àwa sì ni Olódodo.

Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ nígbà náà pé: “Olúwa yín ni Oníkẹ̀ẹ́ tó gbòòrò. Kò sì sí ẹni tó lè gbé ìyà Rẹ̀ kúrò lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Àwọn tó ń ṣẹbọ yóò wí pé: “Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni àwa àti àwọn bàbá wa ìbá tí ṣẹbọ, àti pé àwa ìbá tí ṣe n̄ǹkan kan ní èèwọ̀.” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́ títí wọ́n fi tọ́ ìyà Wa wò. Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan ń bẹ ní ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ mú un jáde fún wa?” Ẹ̀yin kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Kí sì ni ẹ̀ ń sọ bí kò ṣe pé ẹ̀ ń parọ́.

Sọ pé: “Ti Allāhu ni ẹ̀rí tó dópin.[1]” Nítorí náà, tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá fi gbogbo yín mọ̀nà pátápátá.”

Sọ pé: “Ẹ mú àwọn ẹlẹ́rìí yín jáde, àwọn tó máa jẹ́rìí pé dájúdájú Allāhu l’ó ṣe èyí ní èèwọ̀.” Tí wọ́n bá jẹ́rìí (irọ́), ìwọ má ṣe bá wọn jẹ́rìí (sí i). Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́. Àwọn sì ni wọ́n ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.

Sọ pé: “Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fún yín pé; kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, - Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn - kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ - èyí tó hàn nínú rẹ̀ àti èyí tó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gban̄dọ́gba.A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ pé ó tabá ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.

Àti pé dájúdájú èyí ni ọ̀nà Mi (tí ó jẹ́ ọ̀nà) tààrà. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú ọ̀nà (mìíràn) nítorí kí ó má baà mu yín yapa ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Rẹ̀).”

Lẹ́yìn náà, A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà ní pípé pérépéré fún ẹni tí ó máa ṣe dáadáa. (Ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan. (Ó tún jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín.

Nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Ọ̀wọ́ ìjọ méjì tí ó ṣíwájú wa ni wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún. A sì jẹ́ aláìnímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ wọn.”

Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún wa ni, àwa ìbá mọ̀nà jù wọ́n lọ.” Ẹ̀rí tó yanjú, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, kò sí ẹni tó ṣàbòsí tó ẹni tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, tó tún gbúnrí kúrò níbẹ̀? A máa san àwọn tó ń gbúnrí kúrò níbi àwọn āyah Wa ní (ẹ̀san) ìyà burúkú nítorí pé wọ́n ń gbúnrí (kúrò níbẹ̀).

Ṣé wọ́n ń retí n̄ǹkan (mìíràn) bí kò ṣe pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí Olúwa rẹ wá bá wọn tàbí kí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ wá bá wọn? Ní ọjọ́ tí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ bá wá bá wọn, ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà). Sọ pé: “Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí (Ọjọ́ náà).

Dájúdájú àwọn tó ya ẹ̀sìn wọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ, ìwọ kò ní n̄ǹkan kan ṣepọ̀ pẹ̀lú wọn. Ọ̀rọ̀ wọn sì ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

Ẹnikẹ́ni tó bá mú iṣẹ́ dáadáa wá, (ẹ̀san) mẹ́wàá irú rẹ̀ l’ó máa wà fún un. Ẹnikẹ́ni tó bá sì mú iṣẹ́ aburú wa, A ò níí san án ní ẹ̀san àyàfi irú rẹ̀. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi ti fi ọ̀nà tààrà (’Islām) mọ̀ mí, ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

Sọ pé: “Dájúdájú ìrun mi, ẹran(pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Kò sí akẹgbẹ́ fún Un. Ìyẹn ni wọ́n pa láṣẹ fún mi. Èmi sì ni ẹni-àkọ́kọ́ àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi).”[1]

Sọ pé: “Ṣé èmi yóò tún wá olúwa kan yàtọ̀ sí Allāhu ni, nígbà tí ó jẹ́ pé Òun ni Olúwa gbogbo n̄ǹkan. Ẹ̀mí kan kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”

Òun ni Ẹni tí Ó ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀. Ó sì fi àwọn ipò gbe yín ga ju ara yín lọ nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fún yín. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”