The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Ranks [As-Saff] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 6
Surah The Ranks [As-Saff] Ayah 14 Location Madanah Number 61
وَإِذۡ قَالَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُم مُّصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيَّ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَمُبَشِّرَۢا بِرَسُولٖ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِي ٱسۡمُهُۥٓ أَحۡمَدُۖ فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ مُّبِينٞ [٦]
(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd.”[1] Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, wọ́n á wí pé: “Idán pọ́nńbélé ni èyí.”