عربيEnglish

The Noble Qur'an Encyclopedia

Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languages

Divorce [At-Talaq] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 2

Surah Divorce [At-Talaq] Ayah 12 Location Madanah Number 65

فَإِذَا بَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ فَارِقُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖ وَأَشۡهِدُواْ ذَوَيۡ عَدۡلٖ مِّنكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلشَّهَٰدَةَ لِلَّهِۚ ذَٰلِكُمۡ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَمَن يَتَّقِ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّهُۥ مَخۡرَجٗا [٢]

Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ parí òǹkà ọjọ́ opó wọn, ẹ mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà tó dára tàbí kí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára.[1] Ẹ fi àwọn onídéédé méjì nínú yín jẹ́rìí sí i. Kí ẹ sì gbé ìjẹ́rìí náà dúró ní tìtorí ti Allāhu. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro).