The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Ascending stairways [Al-Maarij] - Yoruba translation
Surah The Ascending stairways [Al-Maarij] Ayah 44 Location Maccah Number 70
Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1]
Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
Ó máa bó awọ orí tòró.
(Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
Àyàfi àwọn olùkírun,
àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn[1] búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.[1]
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.