The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Clot [Al-Alaq] - Yoruba translation
Surah The Clot [Al-Alaq] Ayah 19 Location Maccah Number 96
Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.
Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.
Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.
Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.
Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà
nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.
Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀
fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!
Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)
tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!
Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?
Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)
Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.[1]) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí² rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);
àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.
Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.
Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).