The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Cow [Al-Baqara] - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Ayah 58
Surah The Cow [Al-Baqara] Ayah 286 Location Madanah Number 2
وَإِذۡ قُلۡنَا ٱدۡخُلُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ فَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ رَغَدٗا وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُولُواْ حِطَّةٞ نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطَٰيَٰكُمۡۚ وَسَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ [٥٨]
(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí.[1] Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.[2] Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.