The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe Cow [Al-Baqara] - Yoruba translation
Surah The Cow [Al-Baqara] Ayah 286 Location Madanah Number 2
’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
Tírà yìí, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
(Àwọn olùbẹ̀rù Allāhu ni:) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìkọ̀kọ̀[1] àti àwọn tó ń kírun àti àwọn tó ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn,
àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ[1] àti àwọn tó ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́.[1]
Allāhu fi èdídí dí ọkàn wọn àti ìgbọ́rọ̀ wọn. Èbìbò sì bo ìríran wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo.
(Wọ́n rò pé) àwọn ń tan Allāhu àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Wọn kò sì tan ẹnì kan bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.
Àrùn kan wà nínú ọkàn wọn[1], nítorí náà Allāhu ṣe àlékún àrùn (náà) fún wọn. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn nítorí pé wọ́n ń parọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Àwa kúkú ni alátùn-únṣe.”
Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òbìlẹ̀jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò fura.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ ní òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́.” Wọ́n á wí pé: “Ṣé kí á gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn òmùgọ̀ ṣe gbàgbọ́ ni?” Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òmùgọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì kù wọ́n ku àwọn (ẹni) ṣaetọ̄n wọn, wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwa ń bẹ pẹ̀lú yín, àwa kàn ń ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”
Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.[1]
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà.[1] Nítorí náà, òkòwò wọn kò lérè, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.
Àpèjúwe wọn dà bí àpèjúwe ẹni tí ó tan iná, ṣùgbọ́n nígbà tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí àyíká rẹ̀ tán, Allāhu mú ìmọ́lẹ̀ wọn lọ, Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àwọn òkùnkùn; wọn kò sì ríran mọ́.
Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; nítorí náà wọn kò níí ṣẹ́rí padà.
Tàbí (àpèjúwe wọn) dà bí òjò ńlá tí ń rọ̀ láti sánmọ̀. Ó mú àwọn òkùnkùn, àrá sísán àti mọ̀nàmọ́ná lọ́wọ́. Wọ́n ń fi ìka wọn sínú etí wọn nítorí àwọn iná láti ojú sánmọ̀ fún ìbẹ̀rù ikú. Allāhu sì yí àwọn aláìgbàgbọ́ ká.
Mọ̀nàmọ́ná náà fẹ́ẹ̀ mú ìríran wọn lọ. Ìgbàkígbà tí ó bá tan ìmọ́lẹ̀ sí wọn, wọ́n á rìn lọ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì ṣóòòkùn mọ́ wọn, wọ́n á dúró si. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá gba ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó dá ẹ̀yin àti àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè máa bẹ̀rù Allāhu (kí ẹ sì lè ṣọ́ra fún ìyà Iná).[1]
(Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí), Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ (fún yín), Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́).
Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Tí ẹ kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò wulẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.
Fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí A bá p’èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: “Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” - Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). - Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Dájúdájú Allāhu kò níí tijú láti fí ohun kan (tí ó mọ) bí ẹ̀fọn tàbí ohun tí ó jù ú lọ ṣàkàwé ọ̀rọ̀. Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò wí pé: “Kí ni ohun tí Allāhu gbàlérò pẹ̀lú àkàwé yìí?” Allāhu ń fi ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Ó sì ń fi tọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sọ́nà. Kò sì níí fi ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àyàfi àwọn arúfin.[1]
(Àwọn arúfin náà ni) àwọn tó ń yẹ májẹ̀mu Allāhu lẹ́yìn tí májẹ̀mu náà ti fìdí múlẹ̀, wọ́n tún ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.[1]
Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun tó wà lórí ilẹ̀ fún yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó dojúkọ (dídá) sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.”[1] Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Ọ. A óò máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọ sẹ́!” Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”
Allāhu fi orúkọ gbogbo n̄ǹkan pátápátá mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ ìwọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ nìkan ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.”[1] Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs.² Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.
A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”[1]
Ni aṣ-Ṣaetọ̄n bá yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: “Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fún yín lórí ilẹ̀ títí di ìgbà kan.”
(Ànábì) Ādam bá rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
A sọ pé[1]: “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.”
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl,[1] ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Ẹ mú májẹ̀mu Mi ṣẹ, Mo máa mú (ẹ̀san) májẹ̀mu yín ṣẹ. Èmi nìkan ni kí ẹ sì páyà.
Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú.[1] Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.
Ẹ má da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì má fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo).
Ẹ kírun, ẹ yọ zakāh, kí ẹ sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun[1]).
Ṣé ẹ̀yin yóò máa pa àwọn ènìyàn l’áṣẹ ohun rere, ẹ sì ń gbàgbé ẹ̀mí ara yín, ẹ̀yin sì ń ké Tírà, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni!
Ẹ wá ìrànlọ́wọ́ (àti oore Allāhu) pẹ̀lú sùúrù[1] àti ìrun kíkí. Dájúdájú ó lágbára (láti ṣe bẹ́ẹ̀) àyàfi fún àwọn olùpáyà (Allāhu),
(Àwọn olùpáyà Allāhu ni) àwọn tó mọ̀ dájúdájú pé, àwọn yóò pàdé Olúwa wọn, àti pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo fi ṣèdẹ̀ra fún yín àti pé dájúdájú Èmí gbọ́lá fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.[1] Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.
(Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami òkun sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún yín,[1] A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.
Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fún yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè máa dúpẹ́ (fún Allāhu).
(Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.[1]
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn tó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fún yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbàgbọ́ nínú rẹ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gbá yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀.
Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).
A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnu[1] àti (ohun jíjẹ) salwā² kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí.[1] Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.² Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.
Ní àwọn tó ṣàbòsí bá yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí ọ̀rọ̀ mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé àwọn tó ṣàbòsí lórí nítorí pé, wọ́n ń rú òfin.
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā tọrọ omi fún ìjọ rẹ̀. A sì sọ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na òkúta.” Orísun omi méjìlá sì ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti mọ ibùmu wọn. Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu nínú arísìkí Allāhu. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí ṣe ìfaradà lórí oúnjẹ ẹyọ kan. Nítorí náà, pe Olúwa rẹ fún wa. Kí Ó mú jáde fún wa nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde ní ewébẹ̀ rẹ̀ àti kùkúḿbà rẹ̀ àti fūmu rẹ̀ (wíìtì àti àlùbọ́sà áyù) àti ọkàbàbà rẹ̀ àti àlùbọ́sà rẹ̀.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò fi èyí tó yẹpẹrẹ pààrọ̀ èyí tí ó dára jùlọ ni? Ẹ sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú (mìíràn). Dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún ń bẹ (níbẹ̀) fún yín.” A sì mú ìyẹpẹrẹ àti òṣì bá wọn. Wọ́n sì padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n sì ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.[1]
Ẹ rántí nígbà tí A gba àdéhùn yín, A sì gbé àpáta wá sókè orí yín, (A sì sọ pé): “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára, kí ẹ sì rántí ohun tó wà nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín, ẹ̀yin ìbá wà nínú ẹni òfò.
Dájúdájú ẹ mọ àwọn tó kọjá ẹnu-ààlà nínú yín nípa ọjọ́ Sabt. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni-ìgbéjìnnà sí ìkẹ́ (ẹni àbùkù ẹni yẹpẹrẹ).”
A sì ṣe é ní ìyà (àríkọ́gbọ́n) fún ẹni tó ṣojú rẹ̀ àti ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Ó tún jẹ́) wáàsí (ìṣítí) fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa abo màálù kan.” Wọ́n wí pé: “Ṣé ò ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ni!” Ó sọ pé: “Mò ń sádi Allāhu kúrò níbi kí n̄g jẹ́ ara àwọn òpè.”
Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ ògbólógbòó, kò sì níí jẹ́ gódógbó. Ọdún rẹ̀ máa wà láààrin (méjèèjì) yẹn. Nítorí náà, ẹ ṣe ohun tí wọ́n ń pa yín láṣẹ.”
Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí àwọ̀ rẹ̀ bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù, aláwọ̀ omi-ọsàn ni. Àwọ̀ rẹ̀ sì máa mọ́ fónífóní, tí ó máa dùn-ún wò lójú àwọn olùwòran.
Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa sẹ́.” Dájúdájú àwọn abo màálù jọra wọn lójú wa. Àti pé dájúdájú, tí Allāhu bá fẹ́, àwa máa mọ̀nà (tí a ó gbà rí i.)”
Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ màálù yẹpẹrẹ tí ó ń kọ ebè sórí ilẹ̀ (tó ń ro oko) àti èyí tí ó ń fomi wọ́n oko. Ó máa ní àlàáfíà, kò sì níí ní àbàwọ́n kan lára.” Wọ́n wí pé: “Nísinsìn yìí lo mú òdodo wá.” Wọ́n sì pa màálù náà. Wọ́n fẹ́ẹ̀ má ṣe é mọ́.
(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.
Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).”[1] Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ.[1] Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé ẹ̀ ń rankàn pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.
Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fún yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀?
Àti pé ó wà nínú wọn, àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, tí wọn kò nímọ̀ nípa Tírà àfi àwọn irọ́. Wọn kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe pé wọ́n ń dá àbá (àròsọ).
Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí ń gbà (gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà tàbí ipò) lórí rẹ̀.
Wọ́n sì wí pé: “Iná kò lè fọwọ́ bà wá tayọ ọjọ́ tó lóǹkà.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ti rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Allāhu ni?”Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Àbí ṣé ẹ̀yin yóò máa pa irọ́ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ Allāhu ni?
Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù.[1] Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn).
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín[1] pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i.
Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin wọ̀nyí lẹ̀ ń pa ara yín. Ẹ tún ń lé apá kan nínú yín jáde kúrò nínú ilé wọn. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àti àbòsí ṣèrànwọ́ (fún àwọn ọ̀tá) lórí wọn. Tí wọ́n bá sì wá ba yín (tí wọ́n ti di) ẹrú, ẹ̀yin ń rà wọ́n padà kúrò lóko ẹrú. Èèwọ̀ sì fẹ̀ẹ̀kan ni fún yín láti lé wọn jáde. Ṣé ẹ̀yin yóò gba apá kan Tírà gbọ́, ẹ sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan? Nítorí náà, kí ni ẹ̀san fún ẹni tó ṣè yẹn nínú yín bí kò ṣe àbùkù nínú ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọjọ́ Àjíǹde, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìyà tó le jùlọ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé.[1] Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì mú àwọn Òjíṣẹ́ wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé lẹ́yìn rẹ̀. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú.[1] A sì fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, Mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Ṣé gbogbo ìgbà tí Òjíṣẹ́ kan bá wá ba yín pẹ̀lú ohun tí ọkàn yín kò fẹ́ ni ẹ ó máa ṣègbéraga? Ẹ sì pe apá kan (àwọn Ànábì) ní òpùrọ́, ẹ sì ń pa apá kan!
وَقَالُواْ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَل لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَقَلِيلٗا مَّا يُؤۡمِنُونَ [٨٨]
Wọ́n sì wí pé: “Èbìbò bò wá lọ́kàn.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn ni, nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Ṣebí díẹ̀ ni wọ́n ń gbàgbọ́.
89. Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn (ìyẹn tírà Taorāt), bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́.[1]
Aburú ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn nípa bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ní ti ìlara pé Allāhu ń sọ (Tírà) kalẹ̀ nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Wọ́n sì padà pẹ̀lú ìbínú (mìíràn) lórí ìbínú (Allāhu tí ó ti wà lórí wọn tẹ́lẹ̀). Ìyà tí í yẹpẹrẹ (ẹ̀dá) sì ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tó wà lẹ́yìn rẹ̀, òhun sì ni òdodo, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?
Àti pé dájúdájú (Ànábì) Mūsā ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.”
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀.” Wọ́n wí pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (rẹ̀).” Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: “Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé tiyín nìkan ni Ilé Ìkẹ́yìn tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu, tí kò sì níí jẹ́ ti àwọn ènìyàn (mìíràn), ẹ tọrọ ikú, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Dájúdájú o máa rí wọn pé àwọn ni ènìyàn tó l’ójú kòkòrò jùlọ nípa ìṣẹ̀mí ayé, (wọ́n tún l’ójú kòkòrò ju) àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ. Ìkọ̀ọ̀kan wọn ń fẹ́ pé tí A bá lè fún òun ní ẹgbẹ̀rún ọdún lò láyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kì í ṣe ohun tí ó máa là á nínú ìyà ni pé, kí Á fún un ní ìṣẹ̀mí gígùn lò. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,[1] (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, mọlāika Jibrīl àti mọlāika Mīkāl, dájúdájú Allāhu ni ọ̀tá fún àwọn aláìgbàgbọ́.”
Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ọ. Ẹnì kan kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ àyàfi àwọn arúfin.
أَوَكُلَّمَا عَٰهَدُواْ عَهۡدٗا نَّبَذَهُۥ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ [١٠٠]
Àti pé ṣé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dá májẹ̀mu kan ni apá kan nínú wọn yóò máa jù ú nù? Rárá, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gan-an ni kò gbàgbọ́.
[1]0[1]. Àti pé nígbà tí Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu dé bá wọn, tí ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú ohun tó wà pẹ̀lú wọn, apá kan nínú àwọn tí A fún ní Tírà gbé Tírà Allāhu jù s’ẹ́yìn lẹ́yìn wọn bí ẹni pé wọn kò mọ̀ (pé àsọọ́lẹ̀ nípa Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà nínú rẹ̀)!
Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn ṣaetọ̄n àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán lásìkò) ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì di kèfèrí, ṣùgbọ́n àwọn ṣaetọ̄n àlùjànnú ni wọ́n di kèfèrí, wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjèèjì, Hārūt àti Mọ̄rūt ní ìlú Bābil.[1] Àwọn mọlāika méjèèjì náà kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n sọ pé: “Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí.” Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ẹ̀san tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore jùlọ (fún wọn), tí wọ́n bá mọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má sọ pé “rọ̄‘inā”. (Àmọ́) ẹ sọ pé “unṭḥurnā”[1], kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́ (ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí fẹ́ kí wọ́n sọ oore kan kan kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Allāhu ló ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
Ohunkóhun tí A bá parẹ́ (tàbí pààrọ̀) nínú āyah kan[1] tàbí tí A sọ di ìgbàgbé, A máa mú èyí tó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan?
Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
Tàbí ẹ fẹ́ máa bèèrè (ọ̀rọ̀kọ́rọ̀) lọ́wọ́ Òjíṣẹ́ yín ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe bèèrè (ọ̀rọ̀kọ́rọ̀) lọ́wọ́ (Ànábì) Mūsā ṣíwájú? Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àìgbàgbọ́ rọ́pò ìgbàgbọ́, dájúdájú ó ti ṣìnà (kúrò) l’ójú ọ̀nà tààrà.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A fún ní Tírà fẹ́ láti da yín padà sípò kèfèrí lẹ́yìn tí ẹ ti ní ìgbàgbọ́ òdodo, ní ti kèéta láti inú ẹ̀mí wọn, (àti) lẹ́yìn tí òdodo (’Islām) ti fojú hàn sí wọn. Nítorí náà, ẹ foríjìn wọ́n, kí ẹ ṣàmójú kúrò fún wọn (nípa ìnira tí wọ́n ń fi kàn yín) títí Allāhu yó fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá (láti jà wọ́n lógun). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh; ohunkóhun tí ẹ bá sì tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín ní rere, ẹ máa bá a lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: “Ẹnì kan kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi ẹni tí ó bá jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.” Ìyẹn ni ohun tí wọ́n ń fẹ́. Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (sínú ’Islām) fún Allāhu,[1] tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (rere) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn.² Wọn kò sì níí banújẹ́.³
Àwọn yẹhudi wí pé: “Àwọn nasọ̄rọ̄ kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn).” Àwọn nasọ̄rọ̄ náà wí pé: “Àwọn yẹhudi kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn.)” Wọ́n sì ń ké Tírà! Báyẹn ni àwọn tí kò nímọ̀ ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Nítorí náà, Allāhu á dájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
Àti pé kò sí ẹni tó ṣàbòsí tó ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà?[1] Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí wọ́n bá dojú yín kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ojú rere Allāhu (ìyẹn ni pé, ẹ ti dojúkọ Allāhu ní ibi tí wọ́n bá pa yín láṣẹ pé kí ẹ dojúkọ kírun.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.[1]
Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.[1]
Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni (Allāhu). Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.
Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná.
Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ kò níí yọ́nú sí ọ títí o fi máa tẹ̀lé ẹ̀sìn wọn. Sọ pé: “Dájúdajú ìmọ̀nà ti Allāhu ni ìmọ̀nà.” Dájúdajú tí o bá sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn èyí tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀ (’Islām), kò níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu.
Àwọn tí A fún ní Tírà (al-Ƙur’ān), wọ́n ń ké e ní kíké ẹ̀tọ́. Àwọn wọ̀nyẹn gbà á gbọ́ ní òdodo. Àwọn tó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìkẹ́ Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiyín).[1]
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣìpẹ̀ kan kò níí wúlò fún un. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.[1]
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa fi àwọn ọ̀rọ̀ kan dán (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wò. Ó sì parí wọn ní pípé. (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Èmi yó ṣe ọ́ ní aṣíwájú fún àwọn ènìyàn.” (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àti nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi.” (Allāhu) sọ pé: “Àdéhùn Mi (láti sọ ẹnì kan di Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì) kò níí tẹ àwọn alábòsí lọ́wọ́.”
(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun).
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì pèsè àwọn èso fún àwọn ará ibẹ̀ (ìyẹn) ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” (Allāhu) sọ pé: “Àti ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò fún un ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mo máa taari rẹ̀ sínú ìyà Iná. Ìkángun náà sì burú.”
(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ismọ̄‘īl gbé àwọn ìpìlẹ̀ Ilé náà dúró. (Wọ́n ṣàdúà pé) “Olúwa wa, gbà á lọ́wọ́ wa, dájúdájú Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Olúwa wa, ṣe wá ní mùsùlùmí fún Ọ. Kí O sì ṣe nínú àrọ́mọdọ́mọ wa ní ìjọ mùsùlùmí fún Ọ. Fi ìlànà ẹ̀sìn wa hàn wá. Kí O sì gba ìronúpìwàdà wa. Dájúdájú Ìwọ ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Aláàánú.
Olúwa wa, gbé dìde nínú wọn Òjíṣẹ́ kan láààrin wọn, (ẹni tí) ó máa ké àwọn āyah Rẹ fún wọn, tí ó máa kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì máa sọ wọ́n di ẹni mímọ́. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”
Kò sí ẹni tí ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run.
(Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ mùsùlùmí.” Ó sọ pé: “Mo jẹ́ mùsùlùmí fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. (Ànábì) Ya‘ƙūb náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìkíní kejì sọ pé): “Ẹ̀yin ọmọ mi, dájúdájú Allāhu yan ẹ̀sìn náà fún yín. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí.”
Tàbí ẹ̀yín jẹ́ ẹlẹ́rìí nígbà tí ikú dé bá (Ànábì) Ya‘ƙūb? Nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ni ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn (ikú) mi?” Wọ́n sọ pé: “Àwa yó máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun rẹ àti Ọlọ́hun àwọn bàbá rẹ, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄ kí ẹ mọ̀nà.” Sọ pé: “Rárá, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (lẹ̀sìn), ó jẹ́ olùdúró-déédé, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú irú ohun tí ẹ gbàgbọ́, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, wọ́n ti wà nínú ìyapa (òdodo). Allāhu sì máa tó ọ (níbi aburú) wọn. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(Ẹ dúró ti) aró Allāhu. Kò sì ẹni tí ó dára ju Allāhu lọ ní aró? Àwa sì ni olùjọ́sìn fún Un.[1]
Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò jà wá níyàn nípa Allāhu ni?” Òun sì ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Àwa (mùsùlùmí) sì ni olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.
Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.”[1] Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Kò sí ẹni tí ó ṣàbòsí tó ẹni tó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn òmùgọ̀ nínú àwọn ènìyàn máa wí pé: “Kí ni ó mú wọn yí kúrò níbi Ƙiblah wọn tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).”
Báyẹn ni A ṣe yín ní ẹ̀ṣà ìjọ tó lóore jùlọ, nítorí kí ẹ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn àti nítorí kí Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín. A kò sì ṣe Ƙiblah tí o wà lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ibùkọjú-kírun bí kò ṣe pé nítorí kí Á lè ṣe àfihàn ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tí ó máa yísẹ̀ padà. Dájúdájú ó lágbára àyàfi fún àwọn tí Allāhu tọ́ sọ́nà. Allāhu kò sì níí fi ìgbàgbọ́ yín ráre. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.
A kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, dájúdájú A óò dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Dájúdájú tí o bá fún àwọn tí A fún ní Tírà ní gbogbo āyah, wọn kò níí tẹ̀lé Ƙiblah rẹ. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ tẹ̀lé Ƙiblah wọn. Apá kan wọn kò sì níí tẹ̀lé Ƙiblah apá kan. Dájúdájú tí o bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, dájúdájú nígbà náà ìwọ wà nínú àwọn alábòsí.
Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́, wọ́n sì mọ̀.
Òdodo náà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.
Ìkọ̀ọ̀kan (ìjọ ẹlẹ́sìn) ló ní ibùkọjúsí tó ń kọjú sí. Nítorí náà, ẹ yára gbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere. Ibikíbi tí ẹ bá wà, Allāhu yóò mú gbogbo yín wá (ní Ọjọ́ Àjíǹde). Dájúdájú Alágbára ni Allāhu lórí gbogbo n̄ǹkan.
Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram, nítorí pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀,[1] nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fún yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.
Gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan si yín láààrin ara yín,[1] tí ó ń ké àwọn āyah Wa fún yín, tí ó ń sọ yín di ẹni mímọ́, tí ó ń kọ yín ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì ń kọ yín ní ohun tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀,
nítorí náà, ẹ rántí Mi, Kí N̄g rántí yín.[1] Ẹ dúpẹ́ fún Mi, ẹ má ṣàì moore sí Mi.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo,ẹ fi sùúrù àti ìrun kíkí tọrọ oore (lọ́dọ̀ Allāhu). Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù.
Ẹ má ṣe pe àwọn tí wọ́n ń pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu (ojú-ogun ẹ̀sìn) ní òkú (ìyà), àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fura.[1]
Dájúdájú A ó máa dán-an yín wò pẹ̀lú kiní kan látara ẹ̀rù, ebi, àdínkù nínú àwọn dúkìá, àwọn ẹ̀mí àti àwọn èso. Kí o sì fún àwọn onísùúrù ní ìró ìdùnnú.
Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.”
Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti ìkẹ́ yó máa bẹ fún láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùmọ̀nà.
Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́[1] Onímọ̀.
Dájúdájú àwọn tó ń daṣọ bo ohun tí A sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìmọ̀nà, lẹ́yìn tí A ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn sínú Tírà, àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ń ṣẹ́bi lé. Àwọn olùṣẹ́bi sì ń ṣẹ́bi lé wọn.
Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni ègún Allāhu, àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) ènìyàn pátápátá ń bẹ lórí wọn.
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).
Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn lórí omi pẹ̀lú (ríru) ohun tó ń ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní omi láti sánmọ̀, tí Ó sì ń fi sọ ilẹ̀ di ààyè lẹ́yìn tí ó ti kú, àti (bí) Ó ṣe fọ́n gbogbo ẹranko ká sí orí ilẹ̀, àti ìyípadà atẹ́gùn[1] àti ẹ̀ṣújò tí A tẹ̀ba láààrin sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.
Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ó ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàbòsí lè rí ìgbà tí wọ́n máa rí Ìyà náà ni, (wọn ìbá mọ̀ pé) dájúdájú gbogbo agbára ń jẹ́ ti Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
(Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (ìyẹn àwọn aṣíwájú kèfèrí) bá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn tó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun tó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá.
Àwọn tó tẹ̀lé wọn yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ìpadàwáyé lè wà fún wa ni, àwa ìbá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa.” Báyẹn ni Allāhu yó ṣe fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n ní (iṣẹ́) òfò fún wọn. Wọn kò sì níí jáde kúrò nínú Iná.
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jẹ nínú ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ (tó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti n̄ǹkan) dáadáa. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
[1]69. Ohun tí ó máa pa yín ní àṣẹ rẹ̀ ni (iṣẹ́) aburú, ìbàjẹ́ àti pé kí ẹ máa pa irọ́ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ Allāhu.
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá, A óò máa tẹ̀lé ohun tí a bá l’ọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò ṣe làákàyè kan kan (nípa ẹ̀sìn), tí wọn kò sì mọ̀nà?
Àpèjúwe àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ dà bí àpèjúwe ẹni tí ó ń kígbe (mọ́ ẹranko) tí kò gbọ́rọ̀ bí kò ṣe ìpè àti igbe (asán). Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; wọn kò sì níí ṣe làákàyè.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín, kí ẹ sì dúpẹ́ fún Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni òkúǹbete[1], ẹ̀jẹ̀², ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun tí wọ́n pe orúkọ mìíràn lé lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.³
Dájúdájú àwọn tó ń daṣọ bo ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú Tírà, tí wọ́n sì ń tà á ní owó pọ́ọ́kú, àwọn wọ̀nyẹn kò jẹ kiní kan sí inú wọn bí kò ṣe Iná. Allāhu kò sì níí bá wọn sọ̀rọ̀ (ìdùnnú) ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà, (wọ́n tún fi) àforíjìn ra ìyà.[1] Ṣé wọn sì lè ṣèfaradà fún Iná! (Àbí kí ló kì wọ́n láyà láti ṣe iṣẹ́ Iná!)
Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé dájúdájú Allāhu sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àwọn tó sì yapa Tírà náà kúkú ti wà nínú ìyapà tó jìnnà (sí òdodo).
Kì í ṣe ohun rere ni pé, kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn,[1] àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni tó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì. Tòhun ti ìfẹ́ tí olùṣe-rere ní sí dúkìá, ó tún ń fi dúkìá náà tọrẹ fún àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù, onírìn-àjò (tí agara dá), àwọn atọrọjẹ àti fún ìtúsílẹ̀ ẹrú l’óko ẹrú. (Ẹni rere) yó máa kírun, yó sì máa yọ Zakāh. (Ẹni rere ni) àwọn tó ń mú àdéhùn wọn ṣẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe àdéhùn. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lásìkò ìpọ́njú, lásìkò àìlera àti l’ójú ogun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe (iṣẹ́) òdodo. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ẹ̀san gbígbà níbi ìpànìyàn ní ọ̀ran-anyàn fún yín. Olómìnira fún olómìnira, ẹrú fún ẹrú, obìnrin fún obìnrin. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò kiní kan fún láti ọ̀dọ̀ arákùnrin rẹ̀ (ìyẹn ni pé, ti aláṣẹ ẹni tí wọ́n pa bá gbà láti gba owó ẹ̀mí dípò fífi ẹ̀mí apànìyàn dí ẹ̀mí ẹni tí wọ́n pa, kí ẹni tí ó gba owó ẹ̀mí dípò ẹ̀mí) ṣe dáadáa tẹ̀lé (owó tí ó gbà, ìyẹn ni pé, kí ó fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba owó ẹ̀mí náà. Àti pé kí ẹni tí ó máa san owó ẹ̀mí) san ań fún un ní ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni ìgbéfúyẹ́ àti àánú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà (òfin) lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.
Ìsẹ̀mí wà fún yín nínú (òfin) ìgbẹ̀san, ẹ̀yin onílàákáyè, kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún yín, nígbà tí (àwọn àmì) ikú[1] bá dé bá ẹnì kan nínú yín, tí ó sì máa fi dúkìá sílẹ̀, pé kí ó sọ àsọọ́lẹ̀² ní ọ̀nà tó dára fún àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí. (Èyí jẹ́) ojúṣe fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
Ẹnikẹ́ni tí ó bá yí i padà lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ ọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yó sì wà lọ́rùn àwọn tó ń yí i padà. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá páyà àìṣe déédé tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó sọ àsọọ́lẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe láààrin (àwọn tí ogún tọ́ sí), nítorí náà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fún yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).
(Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn tó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.[1]
Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀[1] (tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyಠfún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú yín tí oṣù náà bá bá láyé (nínú ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ara),³ kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fún yín, kò sì fẹ́ ìnira fún yín. Ẹ parí òǹkà ọjọ́ (ààwẹ̀ náà), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un.
Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ́ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Nítorí náà, kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà).
Wọ́n ṣe alẹ́ ààwẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín láti súnmọ́ àwọn ìyàwó yín; àwọn ni aṣọ yín, ẹ̀yin sì ni aṣọ wọn. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀ ń tan ara yín jẹ (nípa àìfẹ́ sun oorun ìfẹ́ ní alẹ́ ààwẹ̀). Ó ti gba ìronúpìwàdà yín, Ó sì ṣe àmójúkúrò fún yín. Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ́ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ óò fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) nípasẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ òdodo. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́ (nígbà tí òòrùn bá wọ̀). Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn nígbà tí ẹ bá ń kóra ró nínú àwọn mọ́sálásí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin tí) Allāhu (gbékalẹ̀), ẹ má ṣe súnmọ́ ọn (ẹ má ṣe kọlu àwọn òfin náà). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Rẹ̀).
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ gbé dúkìá lọ bá àwọn adájọ́ (ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀) nítorí kí ẹ lè fi ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ìpín kan nínú dúkìá àwọn ènìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ (pé ìjà àbòsí lẹ̀ ń jà).
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ìlétéṣù. Sọ pé: “Òhun ni (òǹkà) àkókò fún àwọn ènìyàn àti (òǹkà àkókò fún) iṣẹ́ Hajj. Kì í ṣe iṣẹ́ rere (fún yín) láti gba ẹ̀yìn-ìnkùlé wọnú ilé, ṣùgbọ́n (olùṣe) rere ni ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà wọnú ilé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.
Ẹ gbé ogun ẹ̀sìn dìde ní ojú-ọ̀nà Allāhu sí àwọn tó ń gbé ogun dìde sí yín. Kí ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà.[1] Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.
Ẹ pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Kí ẹ sì lé wọn jáde kúrò níbi tí wọ́n ti le yín jáde. Ìfòòró le ju pípa lọ. Ẹ má ṣe jà wọ́n lógun ní Mọ́sálásí Haram títí wọ́n fi máa jà yín lógun nínú rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá jà yín lógun, ẹ jà wọ́n lógun. Báyẹn ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.
Tí wọ́n bá sì jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ gbógun tì wọ́n títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́. Ẹ̀sìn ’Islām yó sì wà (ní òmìnira) fún Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), kò sí ogun mọ́ àyàfi lórí àwọn alábòsí.
Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san.[1] Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-ààlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-ààlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
Ẹ náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun (nípa sísá fún ogun ẹ̀sìn). Ẹ ṣe rere. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.
Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu. Tí wọ́n bá sì se yín mọ́ ojú ọ̀nà, ẹ fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ fá irun orí yín títí di ìgbà tí ẹran ọrẹ náà yó fi dé àyè rẹ̀. Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí ìnira kan ń bẹ ní orí rẹ̀, ó máa fi ààwẹ̀ tàbí sàráà tàbí ẹran pípa ṣe ìtánràn (fún kíkánjú fá irun orí). Nígbà tí ẹ bá fọkànbalẹ̀ (nínú ewu), ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá tó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí wọ́n ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, rírú òfin àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò tó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè.
Kò sí ìbáwí fún yín (níbi òwò ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ hajj) pé kí ẹ wá oore kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ń darí bọ̀ láti ‘Arafah, ẹ ṣe ìrántí Allāhu ní àyè alápọ̀n-ọ́nlé (Muzdalifah). Ẹ ṣe ìrántí Rẹ̀ nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ wà nínú àwọn olùṣìnà.
Lẹ́yìn náà, ẹ dà kúrò láti ibi tí àwọn ènìyàn ti dà kúrò (ìyẹn ní ‘Arafah), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn Allāhu. Dájúdájú, Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Nígbà tí ẹ bá parí ìjọ́sìn (Hajj) yín, ẹ ṣèrántí Allāhu gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń ṣèrántí àwọn baba ńlá yín. Tàbí kí ìrántí náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ayé.” Kò sì níí sí ìpín oore kan fún un ní ọ̀run.
Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tó ń sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”
Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni ìpín oore nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ tó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.[1]
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ̀ yó máa ṣe ọ́ ní kàyéfì nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, tí yó sì máa fi Allāhu jẹ́rìí sí ohun tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀ (pé kò sí ìjà mọ́), oníjà tó le jùlọ sì ni.
Nígbà tí ó bá sì yísẹ̀ padà, ó máa ṣiṣẹ́ káàkiri lórí ilẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀, kí ó sì lè pa n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn run. Allāhu kò sì fẹ́ràn ìbàjẹ́.
Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún un pé: “Bẹ̀rù Allāhu.” Ìgbéraga sì máa mú un dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, iná Jahanamọ yóò tó o (ní ẹ̀san). Ibùgbé náà sì burú.
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ta ẹ̀mí ara rẹ̀ (ìyẹn, olùjagun-ẹ̀sìn) láti wá ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀).
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ kó s’ínú ẹ̀sìn ’Islām pátápátá. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ tẹ̀lé ojú-ẹsẹ̀ aṣ-Ṣaetọ̄n. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
Nítorí náà, tí ẹsẹ̀ yín bá yẹ̀ (kúrò nínú ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé ba yín, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe pé kí Allāhu wá bá wọn nínú ibòji ẹ̀ṣújò funfun,[1] àwọn mọlāika náà (sì máa wá, nígbà náà), A ó sì yanjú ọ̀rọ̀ (ìṣírò iṣẹ́ ẹ̀dá)! Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè pé: “Mélòó ni A ti fún wọn nínú āyah tó yanjú (àmọ́ tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀)?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá (fi àìgbàgbọ́) pààrọ̀ ìdẹ̀ra Allāhu (al-Islām) lẹ́yìn tí ó dé bá a, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.
Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn tó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.[1]
Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (ẹlẹ́sìn ’Islām bẹ̀rẹ̀ lórí Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -). Lẹ́yìn náà, Allāhu gbé àwọn Ànábì dìde, tí wọ́n ń jẹ́ oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa-ẹnu lórí rẹ̀. Kò sì sí ẹni tó yapa-ẹnu (lórí ’Islām) àfi àwọn tí A fún ní Tírà, lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Nítorí náà, Allāhu tọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sọ́nà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ nípa ohun tí (àwọn onílara)[1] yapa-ẹnu lórí rẹ̀ nípa òdodo (’Islām). Allāhu yó máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà.²
Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí irúfẹ́ (àdánwò) tó kan àwọn tó ti lọ ṣíwájú yín kò ì kàn yín? Ìpọ́njú àti àìlera mú wọn. Wọ́n sì rí àmìwò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Òjíṣẹ́ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ fi sọ pé: “Ìgbà wo ni àrànṣe Allāhu máa dé sẹ́?” Kíyè sí i! Dájúdájú àrànṣe Allāhu súnmọ́.
Wọn yóò máa bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yóò máa ná (àti ibi tí àwọn yóò máa ná an sí). Sọ pé: “Ohun tí ẹ bá ná nínú ohun rere, kí ó máa jẹ́ ti àwọn òbí méjèèjì, àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe nínú ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.”
A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé yín lórí, ohun ìkórira sì ni fún yín. Ó sì lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ oore fún yín. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ aburú fún yín. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ogun jíjà nínú oṣù ọ̀wọ̀. Sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ogun jíjà nínú rẹ̀. Àti pé ṣíṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ṣíṣe àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, dídí àwọn mùsùlùmí lọ́wọ́ láti wọ inú Mọ́sálásí Haram àti lílé àwọn mùsùlùmí jáde kúrò nínú rẹ̀, (ìwọ̀nyí) tún tóbi jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu.” Ìfòòró tóbi ju ìpànìyàn. Wọn kò ní yéé gbógun tì yín títí wọn yó fi ṣẹ́ yín lórí kúrò nínú ẹ̀sìn yín, tí wọ́n bá lágbára (ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣẹ́rí kúrò nínú ẹ̀sìn rẹ̀, tí ó sì kú sí ipò kèfèrí, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó gbé ìlú (wọn) jù sílẹ̀ àti àwọn tó jagun ẹ̀sìn ní ojú-ọ̀nà Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ń retí ìkẹ́ Allāhu. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Aláàánú.
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọtí àti tẹ́tẹ́. Sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi àti àwọn àǹfààní kan wà nínú méjèèjì fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì sì tóbi ju àǹfààní wọn.”[1] Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yó máa ná ní sàráà. Sọ pé: “Ohun tí ó bá ṣẹ́kù lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbọ́ bùkátà inú ilé tán (ni kí ẹ ṣe sàráà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀
nípa ayé àti ọ̀run. Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ọmọ òrukàn. Sọ pé: “Ṣíṣe àtúnṣe dúkìá wọn (láì níí dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín) l’ó dára jùlọ. Tí ẹ bá sì dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín, ọmọ ìyá yín (nínú ẹ̀sìn) kúkú ni wọ́n. Allāhu sì mọ òbìlẹ̀jẹ́ yàtọ̀ sí alátùn-únṣe. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (kí ẹ ya dúkìá wọn sí ọ̀tọ̀ nìkan ni) ìbá kó ìnira ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”
Ẹ má fi àwọn abọ̀rìṣà lóbìnrin ṣaya títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú ẹrúbìnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lóbìnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lóbìnrin wù yín.[1] Ẹ má sì fi onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin fún àwọn abọ̀rìṣà lọ́kùnrin títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹrúkùnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lọ́kùnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lọ́kùnrin wù yín. Àwọn (abọ̀rìṣà) wọ̀nyẹn ń pèpè sínú Iná. Allāhu sì ń pèpè sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.
Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnira[1] ni (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìmọ́ra, ẹ súnmọ́ wọn ní àyè tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra.”²
Oko yín ni àwọn obìnrin yín (ìyẹn àwọn ìyàwó yín). Ẹ lọ s’ínú oko yín bí ẹ bá ṣe fẹ́, kí ẹ sì ti (iṣẹ́ rere) ṣíwájú fún ẹ̀mí ara yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ máa pàdé Rẹ̀. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.
Ẹ má ṣe fi Allāhu ṣe ìkẹ́wọ́ fún ìbúra yín pé ẹ kò níí ṣe rere, ẹ kò níí ṣọ́ra (níbi ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ẹ kò sì níí ṣe àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá ti inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Onísùúrù.
Ìkóraró fún oṣù mẹ́rin wà fún àwọn tó búra pé àwọn kò níí súnmọ́ obìnrin wọn. Tí wọ́n bá ṣẹ́rí padà (láààrin ìgbà náà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláàánú.[1]
Tí wọ́n bá sì pinnu ìkọ̀sílẹ̀, (kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóraró fún héélà mẹ́ta.[1] Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti fi ohun tí Allāhu ṣ’ẹ̀dá (rẹ̀) sí inú àpò-ọmọ wọn pamọ́, tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àwọn ọkọ wọn ní ẹ̀tọ́ sí dídá wọn padà láààrin (àsìkò) yẹn, tí wọ́n bá gbèrò àtúnṣe. Àwọn ìyàwó ní ẹ̀tọ́ l’ọ́dọ̀ ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí àwọn ọkọ wọn ní l’ọ́dọ̀ wọn lọ́nà tó dára. Ipò àjùlọ tún wà fún àwọn ọkùnrin lórí wọn.² Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀).[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.
Nítorí náà, tí ọkọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kẹta), obìnrin náà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i mọ́ lẹ́yìn náà títí obìnrin náà yóò fi fẹ́ ẹlòmíìràn. Tí ẹni náà bá tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì nígbà náà láti padà sí ọ̀dọ̀ ara wọn, tí àwọn méjèèjì bá ti lérò pé àwọn máa ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ (fún wọn), tí Ó ń ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ tó nímọ̀.
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí àsìkò (opó) wọn súnmọ́ kó parí, ẹ lè mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ (ní ìparí opó wọn) pẹ̀lú dáadáa. Ẹ má ṣe mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà ìnira láti lè tayọ ẹnu-ààlà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, ó kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín àti ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún yín nínú Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí Ó ń fi ṣe ìṣítí fún yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.[1]
Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà tó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún.[1] Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà tó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sílẹ̀, àwọn ìyàwó wọn yóò kóraró fún oṣù mẹ́rin àti ọjọ́ mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n bá sì parí àsìkò (opó) wọn, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí wọ́n bá ṣe fúnra wọn (láti ní ọkọ mìíràn) ní ọ̀nà tó dára. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ pẹ́sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí tí ẹ fi pamọ́ sínú ẹ̀mí yín. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin ọkùnrin yó máa rántí wọn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀, àyàfi pé kí ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ má ṣe pinnu títa kókó yìgì títí àsìkò (opó) máa fi parí. Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Rẹ̀. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Onísùúrù.
Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín, tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, láì tí ì súnmọ́ wọn tàbí láì tí ì sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn ní pàtó. Kí ẹ sì fún wọn ní ẹ̀bùn (ìkọ̀sílẹ̀); kí olùgbòòrò (nínú arísìkí) fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀, kí tálíkà sì fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùṣe-rere.
Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdíwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀) tàbí tí ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀[1] bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin. Kí ẹ sì dúró kírun fún Allāhu ní olùbẹ̀rù Rẹ̀ (láì sì níí sọ̀rọ̀ tó jẹmọ́ tayé lórí ìrun).
Ṣùgbọ́n tí ẹ bá ń bẹ̀rù (ọ̀tá l’ójú ogun ẹ̀sìn), ẹ kírun yín lórí ìrìn (ẹsẹ̀) tàbí lórí n̄ǹkan ìgùn. Nígbà tí ọkàn yín bá balẹ̀, ẹ rántí Allāhu (ẹ kírun) gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ (tẹ́lẹ̀) mọ̀ yín.
Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sáyé lọ, kí wọ́n sọ àsọọ́lẹ̀ ìjẹ-ìmu ọdún kan fún àwọn ìyàwó wọn, láì sì níí lé wọn jáde kúrò nínú ilé wọn. Tí wọ́n bá sì jáde (fúnra wọn lẹ́yìn ìjáde opó), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí wọ́n bá fi’ra wọn ṣe ní dáadáa (láti ní ọkọ mìíràn). Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
N̄ǹkan ìgbádùn ní ọ̀nà tó dára tún máa wà fún àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀sílẹ̀. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu.
Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un).[1]
Ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá tó dára, kí Allāhu sì ṣe àdìpèlé (ẹ̀san) fún un ní àdìpèlé púpọ̀? Allāhu ń ká ọrọ̀ nílẹ̀, Ó sì ń tẹ́ ẹ sílẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n sọ fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣeé ṣe pé tí wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán, ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: “Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!” Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.
Ànábì wọn sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Allāhu ti gbé Tọ̄lūt dìde fún yín ní ọba.” Wọ́n wí pé: “Báwo ni ó ṣe lè jẹ ọba lé wa lórí nígbà tí ó jẹ́ pé àwa ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba jù ú lọ? Wọn kò sì fún un ní owó púpọ̀?” Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ṣà á lẹ́ṣà le yín lórí. Ó sì fún un ní àlékún púpọ̀ nínú ìmọ̀ àti okun ara. Allāhu ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ìjọba Rẹ̀. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”
Ànábì wọn tún sọ fún wọn pé: “Dájúdájú àmì ìjọba rẹ̀ ni pé, àpótí yóò wá ba yín. N̄ǹkan ìfàyàbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti ohun tó ṣẹ́kù nínú ohun tí àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā àti ènìyàn (Ànábì) Hārūn fi sílẹ̀ ń bẹ nínú àpótí náà. Àwọn mọlāika máa rù ú wá (ba yín). Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”
Nígbà tí Tọ̄lūt jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu máa fi odò kan dan yín wò. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú rẹ̀, kì í ṣe ẹni mi. Ẹni tí kò bá tọ́ ọ wò dájúdájú òun ni ẹni mi, àyàfi ẹni tí ó bá bu ìwọ̀n ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan mu.” (Ṣùgbọ́n) wọ́n mu nínú rẹ̀ àfi díẹ̀ nínú wọn. Nígbà tí òun àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ sọdá odò náà, wọ́n sọ pé: “Kò sí agbára kan fún wa lónìí tí a lè fi k’ojú Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Àwọn tó mọ̀ pé dájúdájú àwọn máa pàdé Allāhu, wọ́n sọ pé: “Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ (ogun) kékeré tó ti ṣẹ́gun ìjọ (ogun) púpọ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù.”
Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”
Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá.
Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Àti pé dájúdájú ìwọ wà lára àwọn Òjíṣẹ́.
Àwọn Òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn, A ṣoore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan. Ó ń bẹ nínú wọn, ẹni tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (tààrà). Ó sì ṣe àgbéga àwọn ipò fún apá kan wọn. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn tó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasọ̄rọ̄).[1] Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú ohun tí A ṣe ní arísìkí fún yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé. Kò níí sí títà-rírà kan nínú rẹ̀. Kò níí sí olólùfẹ́ kan, kò sì níí sí ìṣìpẹ̀ kan (fún àwọn aláìgbàgbọ́). Àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn sì ni alábòsí.[1]
Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀?[1] Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.² Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi.³
Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Allāhu ni Alárànṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Ṣé ìwọ kò wòye sí ẹni tó bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jiyàn nípa Olúwa rẹ̀, nítorí pé Allāhu fún un ní ìjọba? Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” Ó wí pé: “Èmi náà ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Mo sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń mú òòrùn wá láti ibùyọ. Mú un wa nígbà náà láti ibùwọ̀.” Wọ́n sì pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́nu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí (àwọn ilé ibẹ̀) ti dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o ti wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn (ni ìwọ̀nyí jẹ́). Wo eegun (ràkúnmí náà), wo bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”[1]
Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè.” (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (mo gbàgbọ́), ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: “Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”
Àpèjúwe àwọn tó ń ná dúkìá wọn sí ojú-ọ̀nà Allāhu dà bí àpèjúwe kóró èso kan tí ó hu ṣiri méje jáde, tí ọgọ́rùn-ún kóró sì wà lára ṣiri kọ̀ọ̀kan. Allāhu yó ṣe àdìpèlé fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.
Àwọn tó ń ná dúkìá wọn sí ojú-ọ̀nà Allāhu, tí wọn kò sì fi ìrègún àti ìpalára tẹ̀lé ohun tí wọ́n ná, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbẹ̀rù kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Ọ̀rọ̀ rere àti àforíjìn lóore ju sàráà tí ìpalára tẹ̀lé. Allāhu sì ni Ọlọ́rọ̀, Aláfaradà.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi ìrègún àti ìpalára ba àwọn sàráà yín jẹ́, bí ẹni tí ó ń ná dúkìá rẹ̀ pẹ̀lú ṣekárími, kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àpèjúwe rẹ̀ dà bí àpèjúwe àpáta kan tí erùpẹ̀ ń bẹ lórí rẹ̀. Òjò ńlá rọ̀ sí i, ó sì kó erùpẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ pátápátá. Wọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.
Àpèjúwe àwọn tó ń ná dúkìá wọn láti wá ìyọ́nú Allāhu àti (nítorí pé) ó rinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wọn (pé ẹ̀san rere ń bẹ fún àwọn lórí rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu), ó dà bí àpèjúwe ọgbà oko tó wà lórí ilẹ̀ gíga kan, tí òjò ńlá rọ̀ sí, tí àwọn èso rẹ̀ sì yọ jáde ní ìlọ́po méjì. Tí òjò ńlá kò bá sì rọ̀ sí i, ìrì ń ṣẹ̀ sí i. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
Ǹjẹ́ ẹnì kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí kí òun ní ọgbà oko dàbínù àti àjàrà, tí àwọn odò ń ṣàn ní abẹ́ rẹ̀, tí oríṣiríṣi èso tún wà fún un nínú rẹ̀, kí ogbó dé bá a, ó sì ní àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò lágbara (iṣẹ́ oko ṣíṣe), kí atẹ́gùn líle tí iná ń bẹ nínú rẹ̀ kọlu oko náà, kí ó sì jóná? Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah náà fún yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí ẹ ṣe níṣẹ́ àti nínú àwọn n̄ǹkan tí A mú jáde fún yín láti inú ilẹ̀. Ẹ má ṣe gbèrò láti ná nínú èyí tí kò dára. Ẹ̀yin náà kò níí gbà á àfi kí ẹ dijú gbà á. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.[1]
Aṣ-Ṣaetọ̄n ń fi òṣì dẹ́rù bà yín, ó sì ń pa yín ní àṣẹ ìbàjẹ́ ṣíṣe. Allāhu sì ń ṣe àdéhùn àforíjìn àti oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fún yín. Allāhu ní Oníbúọlá, Onímọ̀.
Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀[1], A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè.
Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ìnáwó tàbí (ohunkóhun) tí ẹ bá jẹ́ ní ẹ̀jẹ́, dájúdájú Allāhu mọ̀ ọ́n. Kò sì níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún àwọn alábòsí.
Tí ẹ bá ṣàfi hàn àwọn sàráà, ó kúkú dára. Tí ẹ bá sì fi pamọ́, tí ẹ lọ́ fún àwọn aláìní, ó sì dára jùlọ fún yín. Allāhu sì máa pa nínú àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ìmọ̀nà wọn kò sí lọ́rùn rẹ, ṣùgbọ́n Allāhu ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ mọ̀nà. Ohunkóhun tí ẹ bá ń ná ní ohun rere, fún ẹ̀mí ara yín ni. Ẹ ò sì gbọ́dọ̀ náwó àfi láti fi wá ojú rere Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ná ní ohun rere, A ó san yín ní ẹ̀san (rẹ̀) ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín.
(Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí kí wọ́n lè máa jagun) sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́.[1] Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.
Àwọn tó ń ná dúkìá wọn ní òru àti ní ọ̀sán, ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Àwọn tó ń jẹ èlé kò níí dìde (nínú sàréè) àfi bí ẹni tí aṣ-Ṣaetọ̄n fọwọ́ bà tí ń ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ yó ṣe dìde. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n wí pé: “Òwò ṣíṣe dà bí òwò èlé.” Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀. Ẹnikẹ́ni tí wáàsí bá dé bá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, tí ó sì jáwọ́, tirẹ̀ ni èyí tó ṣíwájú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì padà (síbi òwò èlé), àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Allāhu máa run òwò èlé. Ó sì máa bù sí àwọn ọrẹ. Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n kírun, tí wọ́n sì yọ Zakāh, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì fi ohun tó ṣẹ́kù nínú èlé sílẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
Tí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ mọ̀ pé ogun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (ń bọ̀ wá bá yín). Tí ẹ bá sì ronú pìwàdà, tiyín ni ojú-owó yín. Ẹ kò níí ṣàbòsí (sí wọn). Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí yín.
Tí (onígbèsè) bá jẹ́ ẹni tí ara ń ni, ẹ wò ó níran títí di àsìkò ìdẹ̀ra. Àti pé kí ẹ fị ṣe sàráà (fún un) lóore jùlọ fún yín, tí ẹ bá mọ̀.
Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà ní àwìn fún gbèdéke àkókò kan, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Kí akọ̀wé ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láààrin yín ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí akọ̀wé má ṣe kọ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi mọ̀ ọ́n. Nítorí náà. kí ó ṣe àkọsílẹ̀. Kí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ pè é fún un. Kí ó bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Kò má ṣe dín kiní kan kù nínú rẹ̀. Tí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ bá jẹ́ aláìlóye tàbí aláìsàn, tàbí kò lè pè é (fúnra rẹ̀), kí alámòjúútó rẹ̀ bá a pè é ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí ẹ pe ẹlẹ́rìí méjì nínú àwọn ọkùnrin yín láti jẹ́rìí sí i. Tí kò bá sí ọkùnrin méjì, kí ẹ wá ọkùnrin kan àti obìnrin méjì nínú àwọn ẹlẹ́rìí tí ẹ yọ́nú sí; nítorí pé tí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin méjèèjì bá gbàgbé, ọ̀kan yó sì rán ìkejì létí. Kí àwọn ẹlẹ́rìí má ṣe kọ̀ tí wọ́n bá pè wọ́n (láti jẹ́rìí). Ẹ má ṣe káàárẹ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kéré ni tàbí ó tóbi, títí di àsìkò ìsangbèsè rẹ̀. Ìyẹn ni déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì gbé ìjẹ́rìí dúró jùlọ. Ó tún fi súnmọ́ jùlọ pé ẹ̀yin kò fi níí ṣeyèméjì. Àfi tí ó bá jẹ́ kátà-kárà ojú ẹsẹ̀ tí ẹ̀ ń ṣe ní àtọwọ́dọ́wọ́ láààrin ara yín, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín tí ẹ kò bá ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ẹ wá ẹlẹ́rìí sẹ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà (ọjà àwìn). Wọn kò sì gbọ́dọ̀ kó ìnira bá akọ̀wé àti ẹlẹ́rìí. Tí ẹ bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, dájúdájú ìbàjẹ́ l’ẹ ṣe. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Allāhu yó sì máa fi ìmọ̀ mọ̀ yín. Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun tó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fún yín[1]. Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀.[1] A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”
Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù tó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn tó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.