The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesMuhammad [Muhammad] - Yoruba translation
Surah Muhammad [Muhammad] Ayah 38 Location Madanah Number 47
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà Allāhu, (Allāhu) máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n tún gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, òhun sì ni òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (Allāhu) máa pa àwọn (iṣẹ́) aburú wọn rẹ́, Ó sì máa ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀ wọn sí dáadáa.
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ tẹ̀lé irọ́. Àti pé dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ tẹ̀lé òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi àpèjúwe wọn lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn.
Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi rí wọn pa dáadáa. (Nígbà tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n tán), ẹ dè wọ́n mọ́lẹ̀ sórí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́.1 Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfo.
Ó máa fi ọ̀nà (Ọgbà Ìdẹ̀ra) mọ̀ wọ́n. Ó sì máa tún ọ̀rọ̀ wọn ṣe sí dáadáa.
Ó máa fi wọ́n wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí Ó ti fi mọ̀ wọ́n.[1]
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn ẹ̀yin náà lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin (nínú ẹ̀sìn).
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, ìparun ni fún wọn. (Allāhu) sì máa sọ iṣẹ́ wọn di òfò.
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, (Allāhu) sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Allāhu pa wọ́n rẹ́. Irú rẹ̀ tún wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu ni Olùrànlọ́wọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àwọn aláìgbàgbọ́, kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn.
Dájúdájú Allāhu yóò fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn ń gbádùn, wọ́n sì ń jẹ (kiri) gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran-ọ̀sìn ṣe ń jẹ (kiri). Iná sì ni ibùgbé fún wọn.
Mélòó mélòó nínú àwọn (ará) ìlú tí ó lágbára ju (ará) ìlú rẹ, tí ó lé ọ jáde, tí A sì ti pa wọ́n rẹ́. Kò sì sí alárànṣe kan fún wọn.
Ǹjẹ́ ẹni tí ó wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, ṣé ó dà bí ẹni tí wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn?
Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra èyí tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (nìyí): àwọn omi odò wà nínú rẹ̀ tí kò níí yí padà àti àwọn odò wàrà tí adùn rẹ̀ kò níí yí padà àti àwọn odò ọtí dídùn fún àwọn tó máa mu ún àti àwọn odò oyin mímọ́. Gbogbo èso wà fún wọn nínú rẹ̀ àti àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (Ṣé ẹni tí ó wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra yìí) dà bí olùṣegbére nínú Iná bí, tí wọ́n ń fún wọn ní omi tó gbóná parí mu, tí ó sì máa já àwọn ìfun wọn pútupùtu?
Ó wà nínú wọn, ẹni tí ó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ títí di ìgbà tí wọ́n bá jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ tán, wọn yó sì wí fún àwọn onímọ̀-ẹ̀sìn pé: “Kí l’ó sọ lẹ́ẹ̀ẹ̀ kan ná?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti dí ọkàn wọn pa. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn.
Àwọn tó sì tẹ̀lé ìmọ̀nà, (Allāhu) ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn. Ó sì máa fún wọn ní ìbẹ̀rù wọn (nínú Allāhu).
Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà, tí ó máa dé bá wọn ní òjijì? Àwọn àmì rẹ̀ kúkú ti dé. Nítorí náà, báwo ni ìrántí (yó ṣe wúlò fún) wọ́n nígbà tí ó bá dé bá wọn?
Nítorí náà, mọ̀ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu. Kí o sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ[1] àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Allāhu mọ lílọ-bíbọ̀ yín àti ibùgbé yín.
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ń sọ pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ sūrah kan kalẹ̀?” Nígbà tí wọ́n bá sọ sūrah aláìnípọ́n-na kalẹ̀,[1] tí wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn nínú rẹ̀, ìwọ yóò rí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa wò ọ́ ní wíwò bí ẹni pé wọ́n ti dákú lọ pọnrangandan. Ohun tí ó sì dára jùlọ fún wọn
ni ìtẹ̀lé àṣẹ (Allāhu) àti (sísọ) ọ̀rọ̀ rere. Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà (ìyẹn ogun ẹ̀sìn) sì ti di dandan, wọn ìbá gbà pé Allāhu sọ òdodo, ìbá dára jùlọ fún wọn.
فَهَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن تَوَلَّيۡتُمۡ أَن تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَتُقَطِّعُوٓاْ أَرۡحَامَكُمۡ [٢٢]
Ó súnmọ́ pé tí ẹ̀yin bá kọ̀yìn sí ogun ẹ̀sìn, (ẹ̀ ń lọ sí oko ìparun nìyẹn, ẹ sì máa padà síbi ìwà ìgbà àìmọ̀kan) tí ẹ̀yin yóò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí ẹ óò sì máa já okùn-ìbí yín?[1]
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣẹ́bi lé. Nítorí náà, Ó di wọ́n létí pa. Ó sì fọ́ ìríran wọn.
Ṣé wọn kò níí ronú nípa al-Ƙur’ān ni tàbí àwọn àgádágodo ti wà lórí ọkàn wọn ni?
Dájúdájú àwọn tó pẹ̀yìn dà (sí ’Islām) lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, aṣ-Ṣaetọ̄n ló ṣe ìṣìnà ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì fún wọn ní ìrètí asán nípa ẹ̀mí gígùn.
Ìyẹn nítorí pé (àwọn aláìsàn ọkàn) ń sọ fún àwọn tó kórira ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ (ìyẹn àwọn yẹhudi) pé: “Àwa yóò tẹ̀lé yin nínú apá kan ọ̀rọ̀ náà.”[1] Allāhu sì mọ àṣírí wọn.
Báwo ni (ó ṣe máa rí fún wọn) nígbà tí àwọn mọlāika bá gba ẹ̀mí wọn, tí wọn yó sì máa lù wọ́n lójú, lù wọ́n lẹ́yìn?
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n tẹ̀lé ohun tí ó bí Allāhu nínú. Wọ́n sì kórira ìyọ́nú Rẹ̀. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́.
Tàbí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn ń lérò pé Allāhu kò níí ṣe àfihàn àdìsọ́kàn burúkú wọn ni?
Àti pé tí A bá fẹ́ Àwa ìbá fi wọ́n hàn ọ́, ìwọ ìbá sì mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Dájúdájú ìwọ yóò mọ̀ wọ́n níbi pé wọ́n máa ń pẹ́kọrọ ọ̀rọ̀.[1] Allāhu sì mọ àwọn iṣẹ́ (ọwọ́) yín.
Dájúdájú A máa dan yín wò títí A fi máa ṣàfi hàn àwọn olùjagun-ẹ̀sìn àti àwọn onísùúrù nínú yín. A sì máa gbìdánwò àwọn ìró yín wò.[1]
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n tún yapa Òjíṣẹ́ Allāhu lẹ́yìn tí ìmọ̀nà ti fojú hàn sí wọn, wọn kò lè kó ìnira kiní kan bá Allāhu. (Allāhu) yó sì ba iṣẹ́ wọn jẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (ọ̀rọ̀) Òjíṣẹ́ náà, kí ẹ sì má ṣe ba àwọn iṣẹ́ yín jẹ́.
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, lẹ́yìn náà tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.
Ẹ má ṣe káàárẹ̀, kí ẹ sì má ṣe pèpè fún kòsógunmọ́, nígbà tí ẹ bá ń lékè lọ́wọ́. Allāhu wà pẹ̀lú yín; kò sì níí kó àdínkù bá ẹ̀san àwọn iṣẹ́ yín.[1]
Eré àti ìranù ni ìṣẹ̀mí ayé. (Àmọ́) tí ẹ bá gbàgbọ́ (nínú Allāhu), tí ẹ sì bẹ̀rù (Rẹ̀), Ó máa fún yín ní àwọn ẹ̀san yín. Kò sì níí bèèrè àwọn dúkìá yín (pé kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh).
Tí (Allāhu) bá bèèrè rẹ̀ ní ọwọ́ yín (pé, kí ẹ fi gbogbo rẹ̀ yọ Zakāh), tí Ó sì won̄koko mọ yín, ẹ máa ṣahun. Ó sì máa mú àrùn ọkàn yín jadé (àṣírí yín yó sì tú síta).
Ẹ̀yin náà mà nìwọ̀nyí tí wọ́n ń pè láti náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tó ń ṣahun wà nínú yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣahun, ó ṣe é fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Allāhu ni Ọlọ́rọ̀. Ẹ̀yin sì ni aláìní. Tí ẹ bá gbúnrí, (Allāhu) máa fi ìjọ mìíràn pààrọ̀ yín. Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí dà bí irú yín.