The Noble Qur'an Encyclopedia
Towards providing reliable exegeses and translations of the meanings of the Noble Qur'an in the world languagesThe private apartments [Al-Hujraat] - Yoruba translation
Surah The private apartments [Al-Hujraat] Ayah 18 Location Madanah Number 49
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbawájú mọ́ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura.
Dájúdájú àwọn tó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti ṣàfọ̀mọ́ ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn.
Dájúdájú àwọn tó ń pè ọ́ láti ẹ̀yìn àwọn yàrá[1], ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n ṣe sùúrù títí o máa fi jáde sí wọn ni, ìbá dára jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí arúfin kan bá mú ìró kan wá ba yín, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti mọ òdodo (nípa ọ̀rọ̀ náà) nítorí kí ẹ má baà ṣe àwọn ènìyàn kan ní ṣùtá pẹ̀lú àìmọ̀, kí ẹ má baà di olùkábàámọ̀ lórí ohun tí ẹ ṣe.
Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín.[1] Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (tó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó ara yín sínú wàhálà. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà.
(Èyí jẹ́) oore àjùlọ àti ìdẹ̀ra láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
Tí igun méjì nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo bá ń bá ara wọn jà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì bá sì kọjá ẹnu-ààlà lórí ìkejì, ẹ bá èyí tí ó kọjá ẹnu-ààlà jà títí ó fi máa ṣẹ́rí padà síbi àṣẹ Allāhu. Tí ó bá sì ṣẹ́rí padà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú déédé. Kí ẹ ṣe déédé. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe- déédé.
Ọmọ ìyá (ẹ̀sìn) ni àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹ ṣàtúnṣe láààrin àwọn ọmọ ìyá yín méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí A lè kẹ yín.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín ní ìnagijẹ burúkú. Orúkọ burúkú (tí kò bá òfin ẹ̀sìn mu) burú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àbá dídá. Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni apá kan àbá dídá. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ ní òkú? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.
Àwọn Lárúbáwá oko sọ pé: “A gbàgbọ́ ní òdodo.” Sọ pé: “Ẹ̀yin kò gbàgbọ́ ní òdodo.” Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé: “A gba ’Islām.” níwọ̀n ìgbà tí ìgbàgbọ́ òdodo kò tí ì wọ’nú ọkàn yín. Tí ẹ bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) kò níí dín kiní kan kù fún yín nínú (ẹ̀san) àwọn iṣẹ́ yín. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.
Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa sọ nípa ẹ̀sìn yín fún Allāhu ni (pé ìgbàgbọ́ òdodo ti wà nínú ọkàn yín)?” Allāhu sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Wọ́n ń ṣèrègún lórí rẹ pé àwọn gba ’Islām. Sọ pé: “Ẹ má fi ’Islām yín ṣèrègún lórí mi. Bí kò ṣe pé Allāhu l’Ó máa ṣèrègún lórí yín pé Ó fi yín mọ̀nà síbi ìgbàgbọ́ òdodo tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Dájúdájú Allāhu mọ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.